Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ní April 1, 2022, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí ilé ìjọsìn wọn fúngbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọdún méjì

APRIL 4, 2022
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Ṣèpàdé Pa Dà Lójúkojú

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Ṣèpàdé Pa Dà Lójúkojú

Bẹ̀rẹ̀ láti April 1 2022, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé pa dà lójúkojú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù kọ́kọ́ ba àwọn ará kan láti pàdé pọ̀, inú wọ́n dùn gan-an nígbà tí wọ́n dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣe ni wọ́n ń rẹ́rìn-ín tí omijé ayọ̀ sì ń já bọ́ lójú wọn bí wọ́n ṣe ń fi ìtara kọrin Ìjọba Ọlọ́run.

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn kan máa lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Arákùnrin Krzysztof Hoszowski láti orílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Orí fóònù ni mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, orí Zoom sì ni àwọn ará ti wo bí mo ṣe ṣèrìbọmi. Mo mọ bí ìpàdé ojúkojú ṣe máa ń rí torí pé ọ̀pọ̀ fídíò ni mo ti wò nípa ẹ̀. Inú mi dùn gàn-an nígbà tí mo rí ìfẹ́, ayọ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn ará.”

Nígbà tí àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀ ní March 2020, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé látorí Íńtánẹ̀ẹ̀tì. Àmọ́ ní báyìí, àwọn tí kò lè ṣèpàdé lójúkojú ṣì láǹfààní láti dara pọ̀ lórí Íńtánẹ̀ẹ̀tì.

Arákùnrin Neil Campbell tó wá láti Edinburgh lórílẹ̀-èdè Scotland sọ pé: “Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin nípàdé, ayọ̀ tí mo ní kọjá àfẹnusọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo láǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn ará fúngbà àkọ́kọ́ láti ọdún méjì tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.”

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a tún láǹfààní láti máa ṣèpàdé lójúkojú.​—Sáàmù 84:10.

 

Àǹgólà

Àméníà

Ọsirélíà

Czech Republic

Ecuador

Jámánì

Gíríìsì

Guinea

Japan

Kazakhstan

Màláwì

Netherlands

Philippines

Ròmáníà

Scotland

South Korea

Sípéènì

South Sudan

Thailand