Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Eritrea

 

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Eritrea

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—39

2020-01-10

ERITREA

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì Tó Ti Dàgbà Kú Sẹ́wọ̀n ní Eritrea

Habtemichael Tesfamariam àti Habtemichael Mekonen kú sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018. Wọ́n fi àwọn méjèèjì sẹ́wọ̀n láìtọ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n fojú wọn gbolẹ̀ gan-an lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún mẹ́wàá níbẹ̀.

2020-01-10

ERITREA

Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé tí Ìyà Tó Ń Jẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Eritrea Máa Dé Etí Iléeṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Lágbàáyé

Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Eritrea sọ pé “ìwà ìkà gbáà” ni kéèyàn máa “fúngun mọ́ àwọn èèyàn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀.”