Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

WATCHTOWER LIBRARY

Fi Watchtower Library Sórí Kọ̀ǹpútà Ẹ

Wa Watchtower Library Tó Dé Kẹ́yìn Jáde

O lè ṣe é kí Watchtower Library máa wo orí ìkànnì fúnra rẹ̀ bóyá ohun tuntun ti wà, tàbí kó o fi fáìlì tó ní àwọn ohun tuntun náà gbé àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí Watchtower Library fúnra rẹ láìlo íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ṣe É Kó Máa Wo Orí Ìkànnì Fúnra Rẹ̀ Bóyá Tuntun Ti Wà

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè ṣe é kí Watchtower Library lè máa wo orí ìkànnì fúnra rẹ̀ bóyá ìwé tàbí àpilẹ̀kọ tuntun ti wà.

  1. Nínú Watchtower Library, tẹ Àká Ìwé, kó o wá tẹ Àbùdá kó lè ṣí àpótí Àbùdá fún Àká Ìwé.

  2. Nínú àpótí Àbùdá fún Àká Ìwé, tẹ Ohun Tuntun, kó o wá sàmì sí Wa ohun tuntun jáde gbàrà tó bá ti dé.

  3. Nígbàkigbà tí ohun tuntun bá ti wà lórí ìkànnì, ó máa bi ẹ́ bóyá o fẹ́ kóun wà á jáde. Tẹ YesWatchtower Library lè wà á jáde, kó sì kó àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí kọ̀ǹpútà ẹ.

Máa Fi Ohun Tuntun Sórí Watchtower Library Fúnra Ẹ

O lè fi fáìlì tó ní àwọn ohun tuntun náà gbé àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí Watchtower Library fúnra rẹ. Tó o bá fẹ́ fáìlì yẹn, o lè gbà á látorí Watchtower Library ẹlòmíì tó ti ní àwọn ohun tuntun náà tàbí kó o tẹ bọ́tìnì tó wà nísàlẹ̀ yìí wà á jáde.

Ṣe Ẹ̀dà Àwọn Ohun Tuntun Náà Sójú Kan

Tó o bá fẹ́ ṣe é, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí:

  1. Nínú Watchtower Library, tẹ Help, kó o wá tẹ Manually Update Package àti Create Package.

  2. Yan ibi tó o fẹ́ tọ́jú fáìlì náà sí lórí kọ̀ǹpútà rẹ, kó o wá tẹ Save. Orúkọ fáìlì tí Watchtower Library máa kó àwọn ohun tuntun náà sí máa parí pẹ̀lú “.updatepkg”.

Wa Àwọn Ohun Tuntun Jáde

Tẹ bọ́tìnì tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè mọ̀ bóyá Watchtower Library tó dé kẹ́yìn wà ní èdè rẹ. Tó bá wà, tẹ̀ lé ìtọ́ni tí kọ̀ǹpútà bá fún ẹ kó o lè tọ́jú fáìlì náà sórí kọ̀ǹpútà rẹ.

Fi Fáìlì Tó Ní Ohun Tuntun Sórí Kọ̀ǹpútà Ẹ

Tó o bá fẹ́ fi fáìlì tó ní àwọn ohun tuntun sórí Watchtower Library fúnra ẹ láìlo íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí:

  1. Nínú Watchtower Library, tẹ Help, kó o wá tẹ Manually Update Package àti Apply Package.

  2. Tó bá ti ṣí àpótí File Explorer, wá fáìlì tí orúkọ rẹ̀ parí pẹ̀lú “.updatepkg”. Yàn án, kó o sì tẹ Open kó lè gbé àwọn ohun tuntun náà sórí Watchtower Library.