Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LANGUAGE

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Language (Lórí Android)

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Language (Lórí Android)

JW Language máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn fóònù Android yìí:

  • Àwọn tablet àti fóònù tó jẹ́ Android 4.1 sókè

  • Àwọn fóònù Kindle Fire

Ó lè má ṣiṣẹ́ lórí àwọn fóònù yìí:

  • Àwọn tablet àti fóònù tó jẹ́ Android 4.1 sísàlẹ̀

 

Tó o bá fẹ́ wa ìwé tàbí fídíò jáde nínú JW Language, o lè lo Wi-Fi tàbí kó o lo data orí fóònù ẹ. Níbi ìbẹ̀rẹ̀, tẹ Settings. Kó o wá yan ohun tó o fẹ́ níbi àmì tó dorí kodò tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Download over cellular.

 

Orí àwọn fóònù tó jẹ́ Android 6.0 sókè nìkan lo ti lè mú kí àtẹ́tísí yára tàbí kó falẹ̀. Tẹ Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá tẹ àmì tó dorí kodò tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Global Playback Speed kó o lè mú kí àtẹ́tísí yára tàbí falẹ̀ tó bó o ṣe fẹ́. Tó o bá ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ kan lọ́wọ́, tẹ bọ́tìnì tó máa jẹ́ kó o lè mú kó yára tàbí kó falẹ̀ bó o ṣe fẹ́.

 

Rárá. Tó ò bá fẹ́ kí JW Language jẹ àyè tó pọ̀ lórí fóònù ẹ:

  • Ìtẹ̀jáde tó o fẹ́ nìkan ni kó o wà jáde dípò kó o wa gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà jáde kó o lè máa lò ó tí ò bá sí íńtánẹ́ẹ̀tì

  • Àwọn fídíò tí kò ní jẹ àyè púpọ̀ ni kó o wà jáde

 

Apá text-to-speech (TTS) orí fóònù ẹ ló ń pinnu bí àtẹ́tísí tó wà nínú ìsọ̀rí Grammar ṣe máa rí. Ó lè gba pé kó o wa ètò ìṣiṣẹ́ TTS míì jáde kó o lè máa gbọ́ àtẹ́tísí tó dáa ju tẹ́lẹ̀ lọ ní èdè tó ò ń kọ́. Tó o bá fẹ́ kí àtẹ́tísí tó wà lábẹ́ Grammar yára tàbí falẹ̀, o lè ṣàtúnṣe sí i níbi ìṣètò JW Language.

 

Orí àwọn fóònù tó jẹ́ Android 6.0 sókè nìkan lo ti lè rí àwọn nǹkan kan, bíi mímú kí àtẹ́tísí yára tàbí falẹ̀.

Tún wo: Ṣé JW Language Máa Ṣiṣẹ́ Lórí Fóònù Mi?

 

Primary language ni èdè tó o gbọ́. Tó o bá ti ń ṣètò JW Language sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ, tẹ Primary Language kó o lè yan èdè tó o gbọ́.

Tún wo: Báwo ni mo ṣe lè yí primary language mi pa dà?

 

Tẹ Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá yí èdè primary language rẹ pa dà níbi bọ́tìnì Primary Language.

 

Èdè tó o fẹ́ kọ́ là ń pè ní target language. Tó o bá ti ń sètò JW Language sórí fóònù ẹ, ó máa ní kó o yan èdè tó o fẹ́ kọ́.

Tún wo: Báwo ni mo ṣe lè yí target language mi pa dà?

 

Yan target language míì níbi tó o ti ń yan èdè.

Tún wo: Ṣé mo lè ní target language tó ju ẹyọ kan lọ?

 

Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ní target language, ìyẹn èdè tó o fẹ́ kọ́, tó ju ẹyọ kan lọ. Tẹ bọ́tìnì tí wọ́n fi ń yan èdè, kó o wá yan èdè míì tó o fẹ́ kọ́.

See also: Báwo ni mo ṣe lè yí target language mi pa dà?

 

Tẹ àmì tó-tò-tó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán kan, kó o wá tẹ Add to Collection. Tẹ Create New Collection kó o lè ní ibi tí wàá máa kó nǹkan sí, o sì lè fún un lórúkọ tó o fẹ́. Tó o bá fi ọ̀rọ̀ kún àkójọ ẹ nígbà tó ò ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́, ó máa wa àtẹ́tísí rẹ̀ jáde sórí fóònù ẹ kó o lè lò ó tí ò bá sí íńtánẹ́ẹ̀tì mọ́.

 

Tẹ bọ́tìnì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ kan kó o lè ṣe ẹ̀dà ẹ̀ tàbí kó o yọ ọ́ kúrò. O lè fi mouse tàbí ìka fa àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tó o kó jọ kó o lè tún un tò.

 

Níbi tó o kó ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán jọ sí, tẹ Start Activity kó o lè rí àwọn ìdánrawò tó o lè ṣe:

  • Look: Yan ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé wá tó jẹ́ ìtúmọ̀ ìbéèrè tó bi ẹ́

  • Match: Yan àwọn ọ̀rọ̀ àti àwòrán tó bára mu, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìtúmọ̀ tó bára mu

  • Listen: Tẹ àtẹ́tísí ọ̀rọ̀ kan, kó o wá yan ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ ẹ̀

  • Flash Cards: Wò ó bóyá o mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan kó o tó ní kó gbé ìdáhùn wá. O lè ṣe é kó yára sọ̀rọ̀ tàbí kó falẹ̀. Tẹ àmì àtẹ́tísí kó o lè pa ohùn náà tàbí kó o tàn án.

  • Audio Lessons: Tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Tẹ Edit kí kọ̀ǹpútà lè bá ẹ to àwọn ọ̀rọ̀ náà tàbí kó o tò ó fúnra ẹ.

 

Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá tẹ bọ́tìnì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Show Romanization, kò ní fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ mọ́.

 

Kò sígbà tó ò lè wo ọ̀rọ̀ lórí JW Language, yálà íńtánẹ́ẹ̀tì wà àbí kò sí. Àmọ́ tó o bá ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́, tẹ ọ̀rọ̀ kan kó lè gbé àtẹ́tísí rẹ̀ jáde. Tó o bá fẹ́ wa àtẹ́tísí àti fídíò jáde kó o lè máa lò ó tí ò bá sí íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ bọ́tìnì tí wọ́n fi ń wa nǹkan jáde. Tó o bá fẹ́ wa gbogbo àtẹ́tísí àti fídíò tó wà ní èdè tó ò ń kọ́ jáde, lọ síbi tó o ti yan èdè, kó o wá tẹ bọ́tìnì Download All tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ target language.

 

Bẹ́ẹ̀ ni, o lè tọ́jú àwọn ìsọfúnni tó o kó jọ àti ìsọfúnni nípa àwọn ohun tó o fi ètò ìṣiṣẹ́ náà ṣe. Níbi Settings, yan ohun tó o fẹ́ lábẹ́ Back Up and Restore. Tó bá jẹ́ pé o ti tọ́jú ìsọfúnni tẹ́lẹ̀, o lè wà á jáde pa dà nígbàkigbà. Tó bá jẹ́ orúkọ tó o sọ àwọn ìsọfúnni tó o kó jọ sórí fóònù ẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ náà lo so èyí tó o ti tọ́jú tẹ́lẹ̀, tó o bá fẹ́ wa èyí tó o tọ́jú tẹ́lẹ̀ jáde, ṣe ló máa fi rọ́pò èyí tó ti wà lórí fóònù ẹ.

 

Ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọwọ́ JW Language lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó ò bá wá rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́, kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù wa lórí ìkànnì,kó o sì fi ránṣẹ́.