Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni​—Belgium

Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni​—Belgium

Tí ẹnì kan bá di akéde, onítọ̀hún gbà pé ètò ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, ìjọ, ẹ̀ka ọ́fíìsì, àti àwọn àjọ míì tó jẹ́ tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè lo àwọn ìsọfúnni òun lọ́nà tó bófin mu fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn. Tinútinú ni àwọn akéde fún ìjọ ní àwọn ìsọfúnni nípa ara wọn bó ṣe wà nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, èyí á jẹ́ kí wọ́n lè kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn, kí wọ́n sì máa gba ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.​—1 Pétérù 5:2.

Àwọn akéde tún lè fún ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ìsọfúnni míì nípa ara wọn bí wọ́n ṣe ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn. Irú àwọn ìsọfúnni tí wọ́n lè fi sílẹ̀ ni orúkọ, ọjọ́ ìbí, ẹ̀yà akọ tàbí abo, ọjọ́ ìrìbọmi, nọ́ńbà fóònù, àdírẹ́sì tàbí ìsọfúnni nípa bí akéde náà ṣe ń ṣe sí nípa tẹ̀mí, ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ tàbí àǹfààní èyíkéyìí tó ní nínú ètò ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìsọfúnni míì tá a tún lè gbà ni àwọn nǹkan tí onítọ̀hún gbà gbọ́ ní ti ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, tó fi mọ́ àwọn ìsọfúnni ara ẹni míì tó jẹ́ àṣírí. A lè gba àwọn ìsọfúnni ara ẹni yìí, a lè ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, a lè tò ó, a lè kó o jọ, ká tọ́jú rẹ̀, a sì lè lò ó ní àwọn ọ̀nà míì tó jọ èyí tí wọ́n ń gbà lo ìsọfúnni.

Òfin Ààbò Lórí Ìsọfúnni tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ni:

General Data Protection Regulation (EU) 2016/679.

Lábẹ́ Òfin Ààbò yìí, àwọn akéde gbà pé kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo àwọn ìsọfúnni wọn fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn, tó fi mọ́ àwọn nǹkan yìí:

  • láti kópa nínú ìpàdé èyíkéyìí tá à ń ṣe nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí nínú iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tàbí ìgbòkègbodò èyíkéyìí;

  • láti kópa nínú ìpàdé, àpéjọ tàbí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n gba àwòrán tàbí ohùn rẹ̀ sílẹ̀, tí wọ́n sì ta látagbà, kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lè gba àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí;

  • láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a yàn fúnni tàbí láti ṣe ojúṣe èyíkéyìí nínú ìjọ, èyí tó gba pé ká kọ orúkọ akéde àti iṣẹ́ tá a yàn fún un sójú pátákó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà;

  • láti rí i pé ìsọfúnni tó péye nípa wọn wà nínú káàdì Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ;

  • kí àwọn alàgbà nínú ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn, kí wọ́n sì ṣe àbójútó wọn (Ìṣe 20:28; Jákọ́bù 5:​14, 15);

  • láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni tá a lè lo tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá wáyé.

A máa fi àwọn ìsọfúnni ara ẹni pa mọ títí dìgbà tá a bá ṣì ń lò wọ́n fún àwọn ohun tá a sọ lókè yìí tàbí fún àwọn ìdí míì tó bófin mu. Tí akéde kan bá kọ̀ láti fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù Àdéhùn Lórí Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni, kò ní ṣeé ṣe fún ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gbé onítọ̀hún yẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ó lè wúlò fún àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ tàbí nínú àwọn ìgbòkègbodò míì nínú ìjọsìn wa.

Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fi àwọn ìsọfúnni ẹni kan ránṣẹ́ sí èyíkéyìí lára àwọn àjọ míì tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Àwọn akéde mọ̀ pé tó bá dọ̀rọ̀ ààbò ìsọfúnni, àwọn kan lára àwọn àjọ tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láwọn orílẹ̀-èdè kan lè ní àwọn òfin tó yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́. Àmọ́, àwọn akéde mọ̀ pé ibi yòówù ká fi ìsọfúnni wọn ránṣẹ́ sí, tó fi mọ́ àwọn àjọ míì tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n máa tè lé Ìlànà Pípa Ìsọfúnni Mọ́ Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé.

Àwọn akéde lẹ́tọ̀ọ́ láti yẹ àwọn ìsọfúnni wọn tó wà lọ́wọ́ ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò, wọ́n lè sọ pé ká pa nǹkan kan rẹ́, wọ́n lè ní ká má lo àwọn ìsọfúnni kan, wọ́n sì lè ní ká ṣàtúnṣe sí àwọn ìsọfúnni kan tí kò péye. Ìgbàkigbà làwọn akéde lè sọ pé àwọn ò gbà kí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo àwọn kan lára ìsọfúnni àwọn mọ́. Àmọ́ ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì lè lẹ́tọ̀ọ́ láti máa lo àwọn kan lára ìsọfúnni rẹ̀ lọ, fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa àti ní àwọn ọ̀nà míì tó bófin mu tó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá máa jẹ́ ará ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé tàbí lórí ìpìlẹ̀ míì tó bófin mu bó ṣe wà nínú Òfin Ààbò Lórí Ìsọfúnni. Àwọn akéde mọ̀ pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó bá ń kọ wọ́n lóminú nípa ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lórí ìsọfúnni wọ́n fún àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ààbò ìsọfúnni lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti dáàbò bo àwọn ìsọfúnni ara ẹni tó wà níkàáwọ́ wọn ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ààbò Lórí Ìsọfúnni. Àwọn akéde mọ̀ pé ìwọ̀nba àwọn èèyàn ló láṣẹ láti yẹ àwọn ìsọfúnni wọn wò, kí wọ́n sì lò ó fún àwọn nǹkan tá a sọ lókè yìí.

Kí ẹni tó bá ní ìbéèrè lórí ọ̀rọ̀ ààbò ìsọfúnni kọ ọ̀rọ̀ orí kọ̀ǹpútà (e-mail) ránṣẹ́ sí ẹni tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ààbò ìsọfúnni lórí àdírẹ́sì yìí:

DataProtectionOfficer.BE@jw.org.

Àwọn akéde mọ̀ pé wọ́n lè rí bí àwọn ṣe lè kàn sí àwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìsọfúnni àti àwọn míì tó ń ṣojú fún wọn ní abala Ìlànà Pípa Àṣírí Mọ́ Láwọn Orílẹ̀-Èdè ní orí ìkànnì jw.org/yo.

Àwọn àyípadà tó ń dé bá òfin àti ìmọ̀ ẹ̀rọ àti àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn wa lè mú kó pọn dandan fún wa láti ṣe àwọn àtúnṣe kan sí bá a ṣe ń lo àwọn ìsọfúnni. Torí náà nígbàkigbà tá a bá ṣe àtúnṣe sí ìlànà Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni, a máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ lórí abala yìí, kí ẹ̀yin náà lè mọ àwọn nǹkan tá à ń ṣe. A rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ máa wá sórí abala yìí látìgbàdégbà kẹ́ ẹ lè mọ àwọn àyípadà tá a bá ṣe.