Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìlànà Nípa Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni

Ìlànà Nípa Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni

LÍLO ÌSỌFÚNNI ARA ẸNI

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan lo lè ṣe lórí ìkànnì yìí láìjẹ́ pé o ṣí àkáǹtì sórí ìkànnì yìí tàbí fi ìsọfúnni èyíkéyìí ránṣẹ́ sí wa. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà lórí ìkànnì yìí tó jẹ́ pé kìkì àwọn tó ṣí àkáǹtì sórí rẹ̀ nìkan ló lè lò ó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó fẹ́ béèrè fún nǹkan kan tàbí tó fẹ́ fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́ tàbí tí ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ fi ìsọfúnni ẹnì kan ránṣẹ́ láti orí ìkànnì jw.org. A máa lo ìsọfúnni rẹ fún ohun tó o gbà wá láyè láti lò ó fún. Láwọn ipò kan, tó o bá sọ pé o ò gbà pé ká máa lo ìsọfúnni rẹ mọ́, fún àwọn ìdí kan tó bá òfin mu, a ṣì lè máa lo àwọn ìsọfúnni náà nìṣó ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òfin àti ìlànà sọ lórí lílo ìsọfúnni ara ẹni.

Àwọn ìsọfúnni tó o fi ránṣẹ́ sí wa lórí ìkànnì wa ni a máa lò fún kìkì ohun tó o sọ pé ká lò ó fún nígbà tó o fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí wa. Àwọn ohun tó o lè tìtorí rẹ̀ fi ìsọfúnni rẹ ránṣẹ́ sí wa rèé:

Àkáǹtì Orí Ìkànnì Yìí. Àdírẹ́sì lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ̀tì, tá a ń pè ní e-mail, tó o tẹ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ò ń ṣí àkáǹtì lórí ìkànnì yìí la ó máa fi bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa àkáǹtì tó o ṣí sórí ìkànnì yìí. Bí àpẹẹrẹ, tí o bá gbàgbé orúkọ tó ò ń lò tàbí ọ̀rọ̀ ìwọlé rẹ, tó o sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́, inú àdírẹ́sì lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà ní abala ìsọfúnni nípa rẹ la máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Fọ́ọ̀mù. Tó o bá fara mọ́ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àtàwọn ìlànà wọn, o lè jẹ́ kó o tóótun láti ṣí àkáǹtì lórí ìkànnì yìí, kó o sì lò ó láti fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́ sí wa tàbí kí ìjọ rẹ lo ìkànnì yìí láti bá ẹ fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́ tó o bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ. Lára àwọn ìsọfúnni tó wà lórí fọ́ọ̀mù náà lè wá látọwọ́ rẹ, àwọn alàgbà ìjọ tàbí alábòójútó àyíká. A máa lo àwọn ìsọfúnni tó o fi ránṣẹ́ láti ṣiṣẹ́ lórí fọ́ọ̀mù rẹ àti fún àwọn ètò tó jẹ mọ́ ọn, títí kan bá a ṣe máa ṣí àyè kan fún ọ nígbà tá a bá ń forúkọ rẹ sílẹ̀. Tó bá pọn dandan, a lè fi àwọn ìsọfúnni tó wà lórí fọ́ọ̀mù rẹ ránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀ka wa míì, oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn àjọ míì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé. Bó ti wù kó jẹ́, ìkọ̀ọ̀kan la máa ń gbé fọ́ọ̀mù àwọn tó forúkọ sílẹ̀ yẹ̀ wò, a kì í ṣe é lápapọ̀.

Ọrẹ. Tó o bá fowó ṣètọrẹ lórí ìkànnì yìí, a máa gba orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ. Káwọn èèyàn bàa lè rọ́nà lo káàdì tá a fi ń rajà láti fi ṣètọrẹ, a máa ń lo àwọn ìkànnì tá a fi ń sanwó, ìyẹn àwọn tó lórúkọ lára wọn, tí wọn kì í sì í fi ìsọfúnni àwọn èèyàn tàfàlà. Ó ṣeé ṣe ká rí ìsọfúnni tó o fi ránṣẹ́ gbà nípa nọ́ńbà àkáǹtì rẹ̀ tàbí nọ́ńbà káàdì tó o fi ń sanwó èyí táá jẹ́ ká lè rí ọrẹ tó fi ránṣẹ́ gbà bóyá ní báńkì. Síbẹ̀, mọ̀ dájú pé ètò ìgbowó tó yanrantí tó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Payment Card Industry Data Security Standard (“PCI DSS”) là ń lò láti fi gba ọrẹ tó o fi ránṣẹ́ látinú káàdì rẹ. Báǹkì tó bá gba ọrẹ náà máa tọ́jú ìsọfúnni nípa ọjọ́, iye àti ibi tó o san ọrẹ náà sí sọ́wọ́ wọn fún iye àkókò tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan lábẹ́ òfin. Èyí á jẹ́ ká lè fèsì tó o bá ní ìbéèrè nípa ọrẹ tó o ṣe, ohun tí òfin àkọsílẹ̀ owó sì sọ náà nìyẹn. A ò ní kàn sí ẹ pé kó o fowó kún ọrẹ tó o ṣé.

Ìsọfúnni púpọ̀ sí i tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O tún lè béèrè ìsọfúnni púpọ̀ sí i tàbí kó o béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ láti orí ìkànnì yìí. A máa lo àwọn ìsọfúnni tó o wà lórí fọ́ọ̀mù tó o fi béèrè láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o béèrè fún. Tó bá gba pé ká fi àwọn ìsọfúnni tó fi béèrè ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀ka wa níbòmíì tàbí àwọn àjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ní àwọn orílẹ̀-èdè míì kárí ayé, a máa ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè rí i dájú pé a ṣiṣẹ́ lórí ohun to béèrè fún.

Àwọn Nǹkan Míì. O lè fi ìsọfúnni nípa ara rẹ (bí orúkọ rẹ, àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù rẹ) sórí ìkànnì yìí kó o lè ṣe àwọn nǹkan míì yàtọ̀ sí kó o ṣe ọrẹ tàbí ṣí àkáǹtì tàbí fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn yìí, a máa rí i dájú pé ìdí tá a fi fẹ́ kó o fi ìsọfúnni rẹ ránṣẹ́ sí wa ṣe kedere sí ẹ, àá sì lò ó fún ohun tó o ní ká fi ṣe, a ò ní lò ó fún nǹkan míì yàtọ̀ síyẹn.

A máa ń gba ìsọfúnni ara ẹni, a máa ń tọ́jú rẹ̀, a sì máa ń lò ó fún ohun tí ẹni tó ni ìsọfúnni náà ní ká lò ó fún. A tún máa ń tọ́jú rẹ̀ fún iye àkókò to bá pọn dandan pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin. Ní irú àwọn ipò yìí, tó o bá pinnu pé o ò ní fún wa ní àwọn ìsọfúnni kan tó pọn dandan pé ká lò, ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti lo àwọn apá kan lórí ìkànnì wa tó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni yẹn, ó sì lè má ṣeé ṣe fún wa láti fèsì àwọn nǹkan kan tó béèrè.

Àwọn tó máa ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o béèrè fún àtàwọn amojú ẹ̀rọ íńtánẹ́ẹ̀tì wa tó máa ń ṣe àtúnṣe sí àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà wa máa lè rí ìsọfúnni tó wà lórí fọ́ọ̀mù tó o fi ránṣẹ́ sí wa. A kò ní fún ẹnikẹ́ni ní ìsọfúnni nípa rẹ àyàfi (1) tó bá pọn dandan ká ṣe bẹ́ẹ̀ ká tó lè ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o béèrè fún, tá a sì ti ṣàlàyé fún ẹ ní kedere; (2) tá a bá rí i pé fífi ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ ṣe pàtàkì láti ṣe ohun tó bá òfin àti ìlànà mu (3) láti fi ṣiṣẹ́ lórí ohun kan tí àwọn agbófinró tàbí aláṣẹ béèrè lọ́wọ́ wa; tàbí (4) láti fi wádìí nípa jìbìtì kan tàbí dènà jìbìtì kan. Tó o bá lo ìkànnì yìí, a jẹ́ pé o ti gbà, o sì ti fara mọ́ ọn pé ká fi ìsọfúnni rẹ ránṣẹ́ sí àwọn ìkànnì míì tá a yá lò fún àwọn ohun tá a ti mẹ́nu kàn yìí. A kò ní ta ìsọfúnni rẹ tàbí fi gba pààrọ̀ pẹ̀lú ìsọfúnni míì tàbí yá àwọn míì lò.

FÍFI ÌSỌFÚNNI RÁNṢẸ́ SÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ

Àjọ wa ní oríṣiríṣi àwọn ẹ̀ka káàkiri ayé tá à ń lo láti fi jọ́sìn Ọlọ́run. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀rọ íńtánẹ́ẹ̀tì tá à ń lò fún ìkànnì wa wà. A lè fi ìsọfúnni rẹ ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ òkèèrè tí àwọn òfin àti ìlànà wọn lórí ìsọfúnni ara ẹni yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè tí ò ń gbé báyìí. Àmọ́ a máa rí dájú pé a dáàbò bo ìsọfúnni rẹ bá a ṣe ń fi í ránṣẹ́. Ó dá wa lójú pé gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àti àwọn àjọ míì tó ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn máa tẹ̀ lé òfin àti ìlànà wa lórí ìsọfúnni ara ẹni.

Tó o bá ti wọlé sórí ìkànnì wa, tó o sì kà sí wa láti orí ìkànnì náà, a jẹ́ pé o ti fara mọ́ ọn pé a lè fi ìsọfúnni rẹ ránṣẹ́ bá a ṣe sọ lókè yìí.

Ẹ̀TỌ́ RẸ

Ìgbàkigbà tá a bá ṣe ohunkóhun pẹ̀lú ìsọfúnni rẹ, a máa ń ṣe gbogbo ohun tó ba yẹ ká ṣe láti rí i pé ìsọfúnni tó o fún wa pé pérépéré, a sì lò ó fún kìkì ohun tá a tìtorí rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ. O ṣì lè ní àwọn ẹ̀tọ́ kan lórí àwọn ìsọfúnni tó o fi ránṣẹ́ sí wa, àmọ́ ìyẹn sinmi lórí àwọn òfin àti ìlànà tó de irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé. Àwọn ẹ̀tọ́ tó o lè ní rèé:

  • O lè béèrè nípa bá a ṣe gba ìsọfúnni rẹ àti bá a ṣe lò ó ní ìbámu pẹ̀lú òfin tá a tẹ̀ lé;

  • O lè béèrè láti rí ìsọfúnni rẹ tàbí láti dènà pé kí ẹnikẹ́ni má rí i, o sì lè béèrè láti pa á rẹ́ tàbí láti ṣe àtúnṣe sí i tó bá jẹ́ pé kò péye tàbí kò kún tó;

  • Tó o bá ní ìdí tó bófin mu, o lè sọ fún wa pé ká má lo ìsọfúnni rẹ tàbí tá a bá ti lò ó ká má ṣe lò ó mọ́.

Tí orílẹ̀-èdè tó o wà bá ní òfin dáàbò bo ìsọfúnni ara ẹni, tó bá wù ẹ́, o lè béèrè láti rí ìsọfúnni rẹ, láti ṣe àtúnṣe sí i tàbí láti pa á rẹ́ pátápátá. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìsọfúnni nípa ibi tó o lè kàn sí lórí Data Protection Contacts page.

Tó o bá kọ̀wé láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó o sì fún wa ní àwọn ìsọfúnni tó máa jẹ́ ká lè dá àwọn ìsọfúnni rẹ mọ̀, táá sì jẹ́ ká lè wá àwọn ìsọfúnni rẹ jáde, a máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá tá a bá ṣe ohun tó o sọ ó máa ṣàkóbá fún ètò wa tàbí tó lè mú kó ṣòro fún wa láti ní òmìnira ìjọsìn. Àá fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí àwọn ìkànnì tá a yá lò fún àwọn àtúnṣe tó yẹ kí wọ́n ṣe.

Jọ̀wọ́ mọ̀ dájú pé a lè má pa ìsọfúnni rẹ rẹ́ tí ó bá pọn dandan lábẹ́ òfin tàbí tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú òfin ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ètò yìí máa ń tọ́jú ìsọfúnni ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí pé tá a bá pa ìsọfúnni náà rẹ́, ó lè ṣàkóbá fún ètò wa àti ìgbàgbọ́ wa. Tó o bá béèrè pé ká pa ìsọfúnni rẹ rẹ́, a máa kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò bóyá ohun tó béèrè bá òfin àti ìlànà tó de pípa ìsọfúnni ara ẹni mọ́ tí ìjọba ní ká tẹ̀ lé. O láǹfààní láti fa ọ̀rọ̀ náà lé àwọn aláṣẹ àdúgbò rẹ lọ́wọ́ tó o bá ní ohun kan lòdì sí bá a ṣe ń pa ìsọfúnni tó o fi ránṣẹ́ sí wa lórí ìkànnì mọ́.