Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìlànà Lórí Ìsọfúnni Kéékèèké àti Àwọn Ohun Míì Tó Jọ Ọ́

Ìlànà Lórí Ìsọfúnni Kéékèèké àti Àwọn Ohun Míì Tó Jọ Ọ́

Bíi tàwọn ìkànnì míì, tó o bá wá sórí ìkànnì yìí, àwọn ìsọfúnni kan máa wọlé sórí fóònù rẹ, tábúlẹ́ẹ̀tì, tàbí hard drive kọ̀ǹpútà tó bá lè tọ́jú àwọn ìsọfúnni kéékèèké, tàbí àwọn àmì kéékèèké tàbí àwọn ètò míì tó fara jọ ọ́. Ọ̀rọ̀ náà “ìsọfúnni kéékèèké” tá a mẹ́nu kàn nínú Ìlànà yìí gbòòrò gan-an, ó sì ní nínú àwọn nǹkan míì tó jọ ọ́, irú bíi local Storage. Àwọn ìsọfúnni kéékèèké yìí ló ń jẹ́ kí ìkànnì yìí ṣiṣẹ́ dáadáa, òhun ló sì ń jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn ṣe ń lo ìkànnì wa. Àwọn nǹkan tá a máa ń lò láti ṣe àtúnṣe tó yẹ sí ìkànnì wa nìyẹn. A kì í tojú bọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹni tó bá wá sórí ìkànnì wa àfi tí ẹni náà fúnra rẹ̀ bá fi àlàyé nípa ara rẹ̀ sínú ọ̀kan nínú àwọn fọ́ọ̀mù tó wà lórí ìkànnì náà.

Àwọn ìsọfúnni kéékèèké. Oríṣiríṣi ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ló wà, iṣẹ́ wọn sì yàtọ̀ síra, àmọ́ gbogbo wọn ló máa jẹ́ kó o lè gbádùn ìkànnì yìí. Àwọn ìsọfúnni kéékèèké yẹn máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá o ti lo ìkànnì yìí rí, ó sì lè jẹ́ ká rántí àwọn ohun tó o yàn láàyò nígbà tó ò ń lo ìkànnì náà. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi ìsọfúnni nípa èdè tó o yàn pa mọ́, kó lè jẹ́ pé nígbà míì tó o bá pa dà wá sórí ìkànnì yìí, a máa gbé èdè yẹn jáde fún ẹ. A kì í fi àwọn ìsọfúnni kéékèèké tá a gbà sílẹ̀ yìí polówó ọjà.

A lè pín àwọn ìsọfúnni kéékèèké tá a máa ń gbà sílẹ̀ lórí ìkànnì yìí sí ọ̀nà mẹ́ta:

  1. Ìsọfúnni Tó Pọn Dandan. Àwọn ìsọfúnni yìí máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ohun kan lórí ìkànnì yìí, bíi kó o wọlé pẹ̀lú àkáǹtì rẹ tàbí kó o fi fọ́ọ̀mù tó o kọ ọ̀rọ̀ sí ránṣẹ́ lórí ìkànnì. Láìsí àwọn ìsọfúnni kéékèèké yìí, o ò ní rí àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe, bí àpẹẹrẹ, o ò ní lè ṣe ọrẹ lórí ìkànnì. Àwọn ìsọfúnni kéékèèké yìí tún máa jẹ́ ká lè ṣe ohun tí ìwọ fúnra ẹ bá béèrè fún nígbà tó ò ń lo ìkànnì wa. A kì í kó àwọn ìsọfúnni rẹ jọ, ká wá máa fi polówó ọjà fún ẹ tàbí ká máa fi rántí gbogbo ibi tó o dé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

  2. Ìsọfúnni Tó Ṣe Pàtàkì. Àwọn ìsọfúnni yìí máa ń jẹ́ kí ìkànnì wa lè rántí àwọn ohun tó o yàn (bí àpẹẹrẹ, orúkọ tó o fi ń ṣí àkáǹtì rẹ, èdè rẹ tàbí agbègbè tó o wà) ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ gbádùn ìkànnì wa.

  3. Ìsọfúnni Tá A Fi Ń Ṣèwádìí. Àwọn ìsọfúnni yìí máa ń jẹ́ ká mọ báwọn èèyàn ṣe ń lo ìkànnì yìí tó, bí àpẹẹrẹ, iye èèyàn tó ń lò ó tàbí bí wọ́n ṣe ń pẹ́ tó lórí ìkànnì náà. Ohun kan ṣoṣo tó ń mú ká gba ìsọfúnni yìí ni pé ó máa ń jẹ́ ká lè mú kí ìkànnì yìí sunwọ̀n sí i.

Àwọn ìsọfúnni kan wà tó jẹ́ pé ìkànnì wa nìkan ló ń gbà á, òun ló sì pọ̀ jù. Àmọ́ àwọn kan wà tó jẹ́ pé ìkànnì míì ló ń gbà á. Nínú àwọn ìsọfúnni tí ìkànnì wa ń gbà, a máa ń jẹ́ kó hàn kedere tó bá jẹ́ pé ìkànnì míì máa lo ìsọfúnni kan.

Àwọn Àmì orí Ìkànnì. Àwọn abala orí ìkànnì wa lè ní àwọn àmì kéékèèké kan tó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan wà lórí abala yẹn. A máa ń fi àwọn àmì yẹn mọ báwọn èèyàn ṣe ń lo ìkànnì wa tó, àti bóyá ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa.

Lílo Àdírẹ́sì IP. Àdírẹ́sì IP ni nọ́ńbà tí Íńtánẹ́ẹ̀tì fi máa ń dá kọ̀ǹpútà rẹ mọ̀. A máa ń lo àdírẹ́sì IP rẹ àti irú ètò tó o fi ń ṣí ìkànnì (browser) ká bàa lè mọ bó o ṣe ń lo ìkànnì yìí, àti ìṣòro tó o máa ń ní tó o bá ń lo ìkànnì náà, ká bàa lè ṣe àtúnṣe tó yẹ. Àmọ́ àdírẹ́sì IP ò lè jẹ́ ká mọ ẹni tó o jẹ́ àfi tó o bá fi àfikún àlàyé nípa ara rẹ sórí ìkànnì náà.

Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí. Nígbà tó o dé orí ìkànnì yìí, àwọn ìsọfúnni kéékèèké kan ti wọlé sórí ẹ̀rọ tó ò ń lò, ó sì ti fi wọ́n pa mọ́. Bó o ṣe ń lo ìkànnì wa fi hàn pé o fára mọ́ ọn pé ká lo àwọn ìsọfúnni yẹn àtàwọn nǹkan míì tó fara jọ ọ́. Tó ò bá fẹ́ ẹ, tó sì wù ẹ́ láti yọ wọ́n kúrò, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ lórí ẹ̀rọ rẹ. Àmọ́ má gbàgbé pé láì sí àwọn ìsọfúnni yẹn o ò ní lè gbádùn gbogbo nǹkan tó wà nínú ìkànnì yìí. Irú ètò tó o fi ṣí ìkànnì (browser) ló máa pinnu bó o ṣe máa yọ àwọn ìsọfúnni náà. O lè lọ sí abala ìrànlọ́wọ́ (Help) kó o lè mọ púpọ̀ sí i.

Yan ọ̀kan lára àwọn ìkànnì tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o lè rí bá a ṣe ń lo àwọn ìsọfúnni kéékèèké lórí ìkànnì náà.

Tún wo Àwọn Ìsọfúnni Kéékèèké àti Àwọn Ohun Míì Tó Jọ Ọ́ Tí Àwọn Ìkànnì Wa Ń Lò.