Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n

Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n

 Lọ́dún 2011, ọkùnrin kan tó ń wá ibi ìsádi wá sórílẹ̀-èdè Norway láti Eritrea. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé òun ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí lórílẹ̀-èdè òun. Ó ní nígbà tóun ń ṣiṣẹ́ ológun níbẹ̀, òun rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣe kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, kódà nígbà tí wọ́n fúngun mọ́ wọn tàbí tí wọ́n fìyà jẹ wọ́n pàápàá.

 Láàárín kan, nǹkan ṣàdédé yí pa dà, ọkùnrin náà bá ara rẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ibẹ̀ ló ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta tó ń jẹ́ Paulos Eyasu, Negede Teklemariam àti Isaac Mogos tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n látọdún 1994 torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

 Nígbà tí ọkùnrin yìí wà lẹ́wọ̀n, ó fojú ara rẹ̀ rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn. Ó kíyè sí bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ àti bí wọ́n ṣe lawọ́, tí wọ́n sì máa ń fáwọn ẹlẹ́wọ̀n míì lára oúnjẹ wọn pàápàá. Ó rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n bíi tiẹ̀ ṣe jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́, tí wọ́n sì ń pe àwọn míì pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn. Ó tún rí bí wọ́n ṣe kọ̀ nígbà tí wọ́n fún wọn láǹfààní láti yẹhùn lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí wọ́n sì buwọ́ lùwé láti gba òmìnira.

 Ohun tí okùnrin yìí rí wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ìyẹn ló mú kó fẹ́ mọ̀dí tí ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lágbára bẹ́ẹ̀ nígbà tó dé Norway. Torí náà, báwọn Ẹlẹ́rìí ṣe dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ló ní kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé wọn.

 Ní September 2018, ó ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbàkígbà tó bá ráyè kàn sáwọn tó wá láti Eritrea tàbí Sudan, ó máa ń gbà wọ́n níyànjú pé káwọn náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára.