Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Fi Pẹ̀lẹ́tù Dá Àlùfáà Kan Tínú Ń Bí Lóhùn

Wọ́n Fi Pẹ̀lẹ́tù Dá Àlùfáà Kan Tínú Ń Bí Lóhùn

 Nígbà tí alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Artur ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Àméníà. Ó kíyè sí pé wọn ò tíì máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí, ìyẹn ibi tí a ti máa ń pàtẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Kí Artur lè fún àwọn ará níṣìírí láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí, òun àti ìyàwó ẹ̀ Anna pẹ̀lú arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jirayr gbé àpótí ìpàtẹ ìwé ìkẹ́ẹ̀kọ́ Bíbélì sí ìlú kékeré kan. Ibi tí èrò pọ̀ sí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń gbà kọjá ni wọ́n dúró sí.

 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn tó ń kọjá lọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò pẹ́ táwọn alátakò fi bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí ọ̀nà tuntun tá a gbà ń wàásù yìí. Àwọn àlùfáà méjì wá síbẹ̀, ọ̀kan lára wọn sì fi ẹsẹ̀ taari àtẹ náà dà nù láìsọ ohunkóhun. Ló bá bu ìfọ́tí lu Artur, kódà ńṣe ni ìgò ojú Arthur yọ dà nù. Artur, Anna àti Jirayr gbìyànjú láti pẹ̀tù sáwọn àlùfáà náà nínú, àmọ́ pàbó nìsapá wọn já sí. Àwọn àlùfáà náà fi ẹsẹ̀ tẹ àtẹ náà mọ́lẹ̀, wọ́n sì tú gbogbo ìwé wọn ká. Àwọn àlùfáà yìí bú àwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, wọ́n sì lọ.

 Artur, Anna àti Jirayr lọ fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà lágbègbè náà. Wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣókí nípa Bíbélì. Lẹ́yìn náà, wọ́n mú àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta náà lọ sí ọ́fíìsì ọ̀gá ọlọ́pàá kan. Ọ̀gá náà kọ́kọ́ bi wọ́n nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi wá fẹjọ́ sùn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà yí pa dà nígbà tó gbọ́ pé Artur ò jà rárá nígbà tí wọ́n fọ́ ọ létí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó taagun, ó sì lágbára, torí ńṣe lọ̀gá ọlọ́pàá náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi wọ́n léèrè nípa ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Ká tó wí, ká tó fọ̀, odindi wákàtí mẹ́rin ni wọ́n fi jọ sọ̀rọ̀! Ohun tí ọ̀gá ọlọ́pàá náà gbọ́ wú u lórí débi tó fi sọ pé: “Ẹ̀sìn yìí mà yàtọ̀ gan-an o! Èmi náà fẹ́ dara pọ̀ mọ́ yín o!”

Artur àti Anna

 Nígbà tí Artur pa dà sídìí àtẹ ìwé lọ́jọ́ kejì, ọkùnrin kan tó rí ohun tó ṣẹlẹ̀ kọjá wá bá a. Ọkùnrin náà gbóríyìn fún Artur torí bí kò ṣe jà, tó sì dúró jẹ́ẹ́. Ó fi kún un pé ohun tóun rí náà ti jẹ́ kí gbogbo àwọn àlùfáà tẹ́ lọ́wọ́ òun.

 Níròlẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀gá ọlọ́pàá yẹn tún pe Artur wá sí àgọ́ ọlọ́pàá. Àmọ́ kì í ṣe torí ohun tó ṣẹlẹ̀ nídìí àtẹ ìwé, ńṣe ló fẹ́ béèrè àwọn ìbéèrè míì nípa Bíbélì. Àwọn ọlọ́pàá míì sì bá wọn lẹ́nu ọ̀rọ̀ náà.

 Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Artur tún wá sọ́dọ̀ ọ̀gá ọlọ́pàá náà, lọ́tẹ̀ yìí, ó fi díẹ̀ lára àwọn fídíò wa tó dá lórí Bíbélì hàn án. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà ní káwọn ọlọ́pàá míì náà wá wo àwọn fídíò náà.

 Àbí ẹ ò rí nǹkan, ìwà tí kò dáa táwọn àlùfáà hù mú kí ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ Bíbélì fúngbà àkọ́kọ́. Ó sì mú kí wọ́n rí i pé èèyàn dáadáa làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.