Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

“Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Ikú”

“Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Ikú”

 Lọ́dún 2005, ọkọ obìnrin ará Íńdíà kan tó ń jẹ́ Sowbhagya kú. Ọkùnrin yìí máa ń tọ́jú ìyàwó rẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn tó ń jẹ́ Meghana, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta dáadáa. Àmọ́ ní báyìí, kò rọrùn fún Sowbhagya láti rí owó gbọ́ bùkátà òun àti ọmọ rẹ̀.

 Èyí tó burú jù ni pé, àwọn èèyàn ò ṣe dáadáa sí i. Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kà á sí oníbáárà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì ti sọ fún un pé ìnira ni òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ jẹ́ fáwọn. Sowbhagya wá bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kó lè rí ìtùnú, àmọ́ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ fojú ẹni tí ìyà ń jẹ wò ó torí pé kò ní nǹkan kan. Sowbhagya wá bẹ̀rẹ̀ sí wá iṣẹ́ kó lè rówó gbọ́ bùkátà òun àti ọmọ rẹ̀. Àmọ́ gbogbo bó ṣe gbìyànjú tó, kó ríṣẹ́ kankan.

 Sowbhagya sọ pé: “Gbogbo nǹkan wá tojú sú mi, torí náà mo pinnu pé màá para mi. Àmọ́, mo mọ̀ pé tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyà máa jẹ ọmọ mi gan-an. Mo wá pinnu pé ó sàn kí àwa méjèèjì kú.” Sowbhagya wá lọ ra májèlé tó máa gbé jẹ torí ó ronú pé òun ò wúlò àti pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ òun.

 Nígbà tí Sowbhagya ń rìnrìn-àjo pa dà sílé, ó pàdé obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Elizabeth nínú ọkọ̀ ojúurin tó wọ̀, obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí i bá Sowbhagya sọ̀rọ̀. Sowbhagya wá sọ fún un pé òun ń wáṣẹ́, Elizabeth sì sọ pé òun máa bá a wáṣẹ́. Elizabeth tún sọ fún un pé ibi tí òun ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni òun ń lọ báyìí. Ohun tó sọ yìí ya Sowbhagya lẹ́nu torí látìgbà tó ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, kò tíì gbọ́ rí pé àwọn kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Elizabeth wá sọ fún Sowbhagya pé kó wá sọ́dọ̀ òun kí òun lè fi bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án.

 Lẹ́yìn tí Sowbhagya délé, ó ṣì ń ronú láti pa ara ẹ̀. Àmọ́ torí pé ìbátan wọn kan ti mú Meghana rìnrìn-àjò, ó pinnu láti dúró de ọmọ ẹ̀ kí àwọn méjèèjì lè jọ kú lẹ́ẹ̀kan náà.

 Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó lọ sọ́dọ̀ Elizabeth, ìyẹn sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Elizabeth wá fún un ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Sowbhagya fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa orí tó sọ pé “Ibo Làwọn Òkú Wà?” Torí pé kò tíì pẹ́ tí ọkọ ẹ̀ kú ló ṣe fẹ́ mọ ibi táwọn òkú wà. Ọjọ́ yẹn gan-an ni Sowbhagya gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Elizabeth pe Sowbhagya sí àpéjọ agbègbè tí wọ́n fẹ́ ṣe ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, Sowbhagya sì gbà láti lọ. Ọ̀rọ̀ tó gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó pinnu pé òun máa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbàrà tó pa dà sílé lẹ́yìn àpéjọ, ó wá rí iṣẹ́.

 Sowbhagya wá ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lọ. Ní báyìí, ó ti wá ní nǹkan gidi tó lè fi ayé ẹ̀ ṣe dípò kó máa ronú bó ṣe máa pa ara ẹ̀. Ó ṣe ìrìbọmi, nígbà tó sì yá, ọmọ ẹ̀ Meghana náà ṣe ìrìbọmi. Ní báyìí, àwọn méjèèjì ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, Meghana sì ń bá ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì atúmọ̀ èdè tó wà ní orílẹ̀-èdè Íńdíà ṣiṣẹ́ láti ilé.

Sowbhagya àti Meghana rèé

 Inú Sowbhagya àti Meghana dùn gan-an pé Elizabeth bá Sowbhagya sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n pàdé nínú ọkọ̀ ojúurin, tí Elizabeth fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì jẹ́ kó mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́! Bákan náà, wọ́n mọyì bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Meghana sọ pé: “Àwa méjèèjì ò bá ti kú lọ́jọ́ yẹn ká sọ pé a ò kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ní báyìí, ayọ̀ wá kún. Èmi àti màámi ń retí ìgbà tí a má tún rí bàbá mi, tá a sì máa gbá wọn mọ́ra, tá a máa kọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá a sì máa sọ fún wọn bí Jèhófà ṣe gbà wá lọ́wọ́ ikú.”