Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Jagun?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Jagun?

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jagun nítorí àwọn ìdí yìí:

  1.   A fẹ́ ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” wọn ò sì ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

  2.   A fẹ́ ṣègbọràn sí Jésù. Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní gbé ohun ìjà láti jagun.

     Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹ̀ lẹ́ àṣẹ tí Jésù fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “apá kan ayé” ní ti pé wọn kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú. (Jòhánù 17:16) Wọn kì í fi ẹ̀hónú hàn sí àwọn ológun nítorí ohun tí wọ́n ṣe sí wọn tàbí dí àwọn tó fẹ́ wọ iṣẹ́ ológun lọ́wọ́.

  3.   A nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòhánù 13:34, 35) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á di ẹgbẹ́ ará kárí ayé, wọn ò sì ní máa bá àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wọn jagun.—1 Jòhánù 3:10-12.

  4.   À ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Religion and War sọ pé: “Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù kọ̀ láti jagun tàbí wọṣẹ́ ológun,” torí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kò bá ìlànà ìfẹ́ tí Jésù fi lélẹ̀ mu, bẹ́ẹ̀ sì ló tún ta ko àṣẹ tó pa pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa.” Bákan náà, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan lórílẹ̀-èdè Jámánì tó ń jẹ́ Peter Meinhold sọ nípa àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù yẹn pé: “Kristẹni kankan kì í dá a láṣà láti wọṣẹ́ ológun.”

À wúlò fún àwọn aládùúgbò wa

 Àwa Ẹlérìí Jèhófà máa ń wúlò ládùúgbò, a kì í sì yọ ìjọba lẹ́nu níbikíbi tí a bá wà. A bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, torí a tẹ̀ lé òfin Bíbélì tó sọ pé:

  •   “Wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.”—Róòmù 13:1.

  •   “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mátíù 22:21.

 Torí náà, a máa ń pa òfin mọ́, a máa ń san owó orí, a sì máa ń kọ́wọ́ ti ìjọba láti bójú tó ire àwọn ará ìlú.