Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Fàyè Gba Àwọn Ẹ̀sìn Míì?

Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Fàyè Gba Àwọn Ẹ̀sìn Míì?

 A máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia”—láìka ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sí. (1 Pétérù 2:17, Bibeli Mimọ) Bí àpẹẹrẹ, láwọn orílẹ̀-èdè kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún. Síbẹ̀ náà, a kì í sọ fún àwọn olóṣèlú tàbí àwọn aṣòfin pé kí wọ́n dí àwọn ẹlẹ́sìn míì lọ́wọ́ tàbí pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wọn. A kì í sì í ṣe ìpolongo pé kí wọ́n ṣe òfin tó máa mú àwọn èèyàn lọ́ranyàn láti máa hùwà bíi tiwa tàbí kí wọ́n máa ṣe ẹ̀sìn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la fàyè gba àwọn ẹlẹ́sìn míì bí àwa náà ṣe fẹ́ kí wọ́n fàyè gbà wá.—Mátíù 7:12.