Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Bíbélì ni ìwé tí wọ́n tíì pín kiri jù lọ láyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì nífẹ̀ẹ́ sí i. Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tọ́pọ̀ èèyàn fi nífẹ̀ẹ́ sí ìwé yìí?’

Ìwé Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? ṣàlàyé ohun tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tí Bíbélì dá lé. Ìwé yìí ṣe àkópọ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ láti Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe dá gbogbo nǹkan títí dé Ìfihàn tó sọ bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ayé di Párádísè. Ìwé yìí tún jẹ́ ká mọ ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé nínú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, onírúurú àwòrán tó ń wọni lọ́kàn àtàwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ ló wà nínú ẹ̀.

Ka ìwé Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? lórí ìkànnì wa.