Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Eèrà Talamọ́ Ṣe Ń Nu Ìdọ̀tí Ara Rẹ̀

Bí Eèrà Talamọ́ Ṣe Ń Nu Ìdọ̀tí Ara Rẹ̀

 Kó lè ṣeé ṣe fún kòkòrò láti fò, láti gun nǹkan, àti láti mọ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó máa nu ìdọ̀tí tó bá yí i lára. Bí àpẹẹrẹ, tí ìdọ̀tí bá wà lára kiní gbọọrọ méjì tó máa ń wà níbi òkè ojú eèrà, kò ní mọ ọ̀nà tó yẹ kó gbà, á ṣòro fún un láti gba ìsọfúnni látọ̀dọ̀ àwọn eèrà yòókù, kò sì ní lè gbóòórùn dáadáa. Alexander Hackmann tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ẹranko sọ pé: “O ò lè rí kòkòrò tó dọ̀tí. Wọ́n ti mọ bí wọ́n ṣe lè fi ọgbọ́n nu ìdọ̀tí ara wọn kúrò.”

 Rò ó wò ná: Hackmann àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣèwádìí nípa bí eèrà talamọ́ ìyẹn Camponotus rufifemur ṣe máa ń nu ìdòtí ara rẹ̀. Wọ́n rí i pé ńṣe ni eèrà yìí máa ń ká ẹsẹ̀ rẹ̀, kó lè dà bí amúga, á wá ki ọ̀kọ̀ọ̀kan kini gbọọrọ ibi ojú rẹ̀ bọ àárín èsẹ̀ tó ká kò náà, á sì fà á yọ pa dà. Àwọn ibi tó rí gbágun-gbàgun lára ẹsẹ̀ rẹ̀ yẹn máa bá a yọ àwọn ìdọ̀tí tó tóbi kúrò. Àwọn ibi wínníwínní tó wà lára ẹsẹ̀ rẹ̀ tí àyè àárín wọn ò fẹ̀ ju irun kéékèèké ló máa ń fi yọ àwọn ìdọ̀tí tí ò fi bẹ́ẹ̀ tóbi.

 Wo bí eèrà talamọ́ ṣe ń nu ìdọ̀tí ara rẹ̀

 Hackmann àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ gbà pé ọgbọ́n tí àwọn eèrà fi ń nu ìdọ̀tí tó bá wà lára wọn lè wúlò fún àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan kéékèèké tó máa ń wà nínú ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́, wọ́n lè lo irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ láti máa fi yọ ìdọ̀tí kúrò lára wọn, torí tí ìdọ̀tí kékeré bá lọ yí àwọn nǹkan kéékèèké náà, ó lè má ṣiṣẹ́ dáadáa.

 Kí lèrò rẹ: Ṣé bí eèrà talamọ́ ṣe ń nu ìdọ̀tí ara rẹ̀ yìí kàn ṣàdédé wáyé ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?