Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ẹja Dolphin Ṣe Ń Mọ Ohun Tó Ń Lọ Lábẹ́ Omi

Bí Ẹja Dolphin Ṣe Ń Mọ Ohun Tó Ń Lọ Lábẹ́ Omi

 Àwọn ẹja dolphin máa ń rọra dún kẹ́-kẹ́-kẹ́, wọ́n sì máa ń súfèé, wọ́n á wá rọra kẹ́tí kí wọ́n lè mọ ohun tó ń lọ àti ibi tí wọ́n á yà sí lábẹ́ omi. Bí ẹja dolphin onímú gígùn (tí wọ́n ń pè ní Tursiops truncatus) ṣe máa ń ṣe náà nìyẹn, ó sì wú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lórí débi pé wọ́n ti ń ṣe àwọn ẹ̀rọ tó lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ tó ṣeé lò lábẹ́ omi tí wọ́n lè fi mọ ohun tó ń lọ.

 Rò ó wò ná: Ohun tí àwọn ẹja dolphin máa ń ṣe yìí má ń jẹ́ kí wọ́n rí àwọn ẹja míì tó sá pa mọ́ sínú yẹ̀pẹ̀ nísàlẹ̀ omi, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n dá òkúta mọ̀ yàtọ̀ sí ẹja. Keith Brown, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní Heriot-Watt University, ní Edinburgh lórílẹ̀-èdè Scotland, sọ pé ohun míì tí ẹja dolphin tún lè ṣe ni pé téèyàn bá bu oríṣiríṣi omi síbì kan ní nǹkan bíi mítà mẹ́wàá síbi tó wà, ó lè “mọ̀ bóyá omi odò ni àbí omi òkun ni àbí bóyá omi tí wọ́n fi ṣúgà sí ni àbí òróró ni wọ́n dà síbẹ̀.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà máa fẹ́ ṣe àwọn ẹ̀rọ tó lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Tí wọ́n bá bu oríṣiríṣi omi sínú nǹkan kan, tó sì wà ní nǹkan bíi mítà mẹ́wàá síbi tí ẹja dolphin wà, ẹja yìí lè fìyàtọ̀ sí irú omi tó wà níbẹ̀

 Àwọn tó ń ṣèwádìí fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí ẹja dolphin ṣe máa ń rọra dún, tó sì máa ń súfèé àti bó ṣe máa ń kẹ́tí, wọ́n sì gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ ọ́. Wọ́n wá ṣe ẹ̀rọ kan tí wọ́n kó oríṣiríṣi ẹ̀rọ kéékèèké kún inú rẹ̀, wọ́n sì gbé e sínú kiní kan tó rí bíi páìpù tí kò gùn tó mítà kan. Wọ́n wá so ó mọ́ ẹ̀rọ kan tó máa ń rìn lábẹ́ omi, wọ́n fẹ́ kó máa yẹ àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ omi wò, kó máa wá àwọn ohun tí yẹ̀pẹ̀ ti bò mọ́lẹ̀ jáde, bíi wáyà tàbí páìpù abẹ́ ilẹ̀, kó sì máa yẹ àwọn ohun tó bá rí wò láìfara kàn wọ́n. Àwọn tó ṣe ẹ̀rọ yìí rí i pé ó máa wúlò láwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lórí epo rọ̀bì. Ẹ̀rọ tí wọ́n wo ẹja dolphin ṣe yìí máa gbéṣẹ́ ju àwọn ẹ̀rọ tó ti wà tẹ́lẹ̀ lọ, ó máa jẹ́ káwọn onímọ̀ ẹ̀rọ lè gbé irinṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ lò síbi tó dáa jù lábẹ́ omi, wọ́n á sì lè fi mọ̀ tí ohunkóhun bá ṣe irinṣẹ́ wọn, bíi tó bá kàn rọra sán lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Wọ́n á tún lè fi máa mọ̀ tí àwọn páìpù kan tó gba abẹ́ ilẹ̀ bá dí.

 Kí lèrò ẹ? Bí ẹja dolphin ṣe máa ń rọra dún, tó sì máa ń súfèé kó lè mọ ohun tó ń lọ lábẹ́ omi yìí, ṣé ó kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?