Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Moment/Robert D. Barnes via Getty Images

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù

Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù

 Ìgbà kan wà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ronú pé ẹyẹ akùnyùnmù máa ń fi ahọ́n ẹ̀ fa omi dídùn tó wà nínú òdòdó bí ìgbà téèyàn ń fẹnu fa omi. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣèwádìí sí i, wọ́n rí i pé ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pátápátá ni ẹyẹ náà máa ń gbà lá omi tó wà nínú òdòdó.

 Rò ó wò ná: Tí ẹyẹ akùnyùnmù bá fẹ́ mu omi tó wà nínú òdòdó, ṣe ni ahọ́n ẹ̀ máa là sí méjì. Ohun kan wà lára ahọ́n yìí tó sábà máa ń wà ní pípadé, àmọ́ tó bá ti ki ahọ́n ẹ̀ bọ inú omi dídùn, ṣe ni ohun náà máa ṣí, táá sì gba omi dídùn náà sára bí ìgbà tá a bá ki fóòmù bọ omi tó sì gba omi náà sára. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ kí ẹyẹ yìí máa lá omi dídùn náà dípò kó máa fà á fúnra ẹ̀. Tó bá wá yọ ahọ́n nínú omi dídùn náà, ṣe ni ahọ́n ẹ̀ máa padé pa dà, gbogbo omi dídùn tí ahọ́n náà ti gbà sára sì máa lọ sẹ́nu ẹ̀.

 Alejandro Rico-Guevara, Tai-Hsi Fan àti Margaret Rubega tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àkókò tí ẹyẹ yìí fi ń la omi dídùn náà kéré “kódà kéèyàn tó ṣẹ́jú, ó ti lá a tán.” Wọ́n tún sọ pé: ‘Orí ahọ́n ẹyẹ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an torí pé ṣe ló máa ń yíra pa dà bó ṣe ń ki ahọ́n bọ omi dídùn tó sì ń yọ ọ́.’

 Yàtọ̀ síyẹn, ẹyẹ náà kì í lo agbára rárá tó bá fẹ́ la omi yìí. Ṣe ni orí ahọ́n ẹ̀ máa ń ṣí tó sì máa ń padé fúnra ẹ̀ tó bá ti kan omi dídùn.

 Torí pé ahọ́n ẹyẹ akùnyùnmù ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé táwọn bá lè ṣe àwọn ẹ̀rọ tó ń ṣiṣẹ́ bí ahọ́n ẹyẹ yìí, ó máa ṣèrànwọ́ gan-an tó bá kan ọ̀rọ̀ ìṣègùn àtàwọn nǹkan míì. Kódà, wọ́n lè wò ó láti ṣe àwọn ẹ̀rọ tó lè lá epo rọ̀bì àtàwọn kẹ́míkà míì tó bá dà sínú òkun.

 Wo bí ẹyẹ akùnyùnmù ṣe ń yọ ahọ́n ẹ̀ jáde

 Kí lèrò ẹ? Ṣé ahọ́n ẹyẹ akùnyùnmù yìí kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?