Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Mọ̀ Nípa Jẹ́lé-Ó-Sinmi

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Mọ̀ Nípa Jẹ́lé-Ó-Sinmi

 Kí àwọn òbí kan tó gba ibi iṣẹ́ lọ, wọ́n máa ń gbé àwọn ọmọ wọn tí ò tíì bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi, ìyẹn ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé tó dà bíi kíláàsì. Ṣó yẹ kó o gbé ọmọ rẹ lọ síbẹ̀?

 Àwọn ìbéèrè tó yẹ kó o bi ara rẹ

 Bó o bá ń gbé ọmọ rẹ lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi, ǹjẹ́ ó máa mojú rẹ? Ó lè má móju rẹ. Tí ọmọ bá wà ní kékeré, ọpọlọ rẹ̀ máa ń yára dàgbà, èyí sì máa nípa lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn. Torí náà, rí i dájú pé ò ń wà pẹ̀lú ọmọ rẹ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó ní àkókò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà yìí.​—Diutarónómì 6:6, 7.

  •    Kí àwọn òbí tó bá fẹ́ gbé ọmọ wọn lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi ronú lórí bí wọ́n á ṣe jẹ́ kí ọmọ náà mojú àwọn.

 Ṣé ọmọ rẹ á máa ṣe ohun tó o bá fẹ́ tó o bá fi sí jẹ́lé-ó-sinmi? Ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Ìwé Hold On to Your Kids sọ pé: “Bí ọmọ kan bá ṣe túbọ̀ ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ míì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ náà á túbọ̀ máa nípa lórí ẹ̀.

  •    Kí àwọn òbí tó bá fẹ́ gbé ọmọ wọn lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi ronú dáadáa bóyá ọmọ náà á ṣì máa gbọ́ tiwọn.

 Ṣé jẹ́lé-ó-sinmi á jẹ́ kí ọmọ rẹ tètè mọ̀wé tó bá bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé? Àwọn kan sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn míì sọ pé ìyẹn ò ní kó tètè mọ̀wé, ó sì lè máà ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bó ṣe máa mọ̀wé tó. Èyí ó wù kó jẹ́, Penelope Leach tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú àwọn ọmọdé sọ nínú ìwé tó kọ pé: “Má ṣe rò pé ohun tọ́mọ bá kọ́ nílé ìwé lá jẹ́ kó rọ́wọ́ mú tó bá dàgbà, má sì ronú pé àǹfààní kankan wà nínú kọ́mọ tètè bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé. Tó o bá ń ronú bẹ́ẹ̀, o lè má rí àǹfààní tọ́mọ rẹ jẹ látinú ẹ̀kọ́ tíwọ fúnra ẹ̀ kọ́ ọ látìgbà tó o ti bí i.”

  •   Kí àwọn òbí tó bá fẹ́ gbé ọmọ wọn lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi rò ó dáadáa bóyá ó ṣàǹfààní tàbí ó tiẹ̀ pọn dandan.

 Ṣé ìwọ tàbí ẹnì kejì rẹ kúkú máa dúró ti ọmọ nílé? Àwọn tọkọtaya kan wà tó jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló ń ṣiṣẹ́ torí kówó tó ń wọlé lè pọ̀ sí i. Ó yẹ káwọn òbí bi ara wọn pé, ṣé kí owó tó ń wọlé pọ̀ sí i ló ṣe pàtàkì àbí kí ọmọ rí ìtọ́jú tó jíire gbà?

  •   Kí àwọn òbí tó bá fẹ́ gbé ọmọ wọn lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi ronú bóyá wọ́n lè dín ìnáwó kù, kí ọ̀kan lára wọn lè máa dúró ti ọmọ nílé.

 Kẹ́ ẹ tó pinnu bóyá ẹ máa gbé ọmọ yín lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi, ẹ kọ́kọ́ fara balẹ̀ ronú lórí àǹfààní tó wà níbẹ̀ àti àkóbá tó lè ṣe. Tẹ́ ẹ bá wá pinnu pé ẹ̀ẹ́ máa gbé ọmọ yín lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi ńkọ́, kí lẹ lè ṣe?

 Ohun tẹ́ ẹ lè ṣe

 Bíbélì sọ pé “aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Pẹ̀lú ìlànà yẹn lọ́kàn yín, ẹ fara balẹ̀ kẹ́ ẹ tó yan jẹ́lé-ó-sínmi tẹ́ ẹ máa gbé ọmọ yín lọ.

 Ẹ ronú nípa àwọn ohun míì tẹ́ ẹ lè ṣe

  •   Ilé ìtọ́jú ọmọdé làwọn òbí míì máa ń gbé ọmọ wọn lọ, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ilé ẹnì kan táwọn olùtọ́jú bíi mélòó kan wà táwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ ò sì ju mélòó kan lọ.

  •   Àwọn òbí míì máa ń jẹ́ kí mọ̀lẹ́bí wọn kan tàbí ẹni kan táá máa wá bá wọn dúró ti ọmọ nílé.

 Gbogbo ẹ̀ náà ló ní ibi tó dáa sí àti ibi tó kù sí. Ẹ lè gbàmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn òbí míì tó ti mú ọmọ lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.”—Òwe 13:10.

 Tó o bá yàn láti gbẹ́ ọmọ rẹ lọ sí jẹ́lé-ó-sínmi kan ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ . . .

 Wádìí bí ibẹ̀ ṣe rí

  •   Ṣé ìjọba fún wọn níwèé àṣẹ, ṣé wọ́n sì ní àwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé bí òfin ṣe sọ? Báwo ni wọ́n ṣe já fáfá sí, ṣé àwọn kan ti lo ibẹ̀ rí, ṣé wọ́n ń ròyìn ibẹ̀ dáadáa?

  •   Ṣé ibẹ̀ ò dọ̀tí, ṣé kò sì léwu?

  •   Kí ni wọ́n ń fún àwọn ọmọ ṣe níbẹ̀? a

 Wádìí nípa àwọn tó ń tọ́jú ọmọ níbẹ̀

  •   Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wo ni wọ́n fún wọn? Ó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń tọ́jú àwọn ọmọdé, kí wọ́n sì mọ ìtọ́jú pàjáwìrì.

  •   Ṣé o ti dọ́gbọ́n ṣèwádìí bóyá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀daràn?

  •   Ṣé lemọ́lemọ́ ni wọ́n ń pààrọ̀ òṣìṣẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìgbà gbogbo lọmọ rẹ á máa kọ́ láti mọwọ́ olùtọ́jú tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà.

  •   Báwo ni ọmọ tí olùtọ́jú kan ṣoṣo á máa bójú tó níbẹ̀ ṣe pọ̀ tó? Bí olùtọ́jú kan ṣoṣo bá ń bójú tó ọmọ tó pọ̀, a jẹ́ pé ìtọ́jú tí ọmọ rẹ á gbà kò ní tó nǹkan. Ṣùgbọ́n ìtọ́jú tọ́mọ rẹ á nílò sinmi lórí ọjọ́ orí rẹ̀ àti ohun tó lè ṣe.

  •   Ṣé àwọn olùtọ́jú tó wà níbẹ̀ ṣe tán láti gbọ́ tẹ́nu ẹ tó o bá kíyè sí nǹkan kan, ṣé àwọn náà sì ṣe tán láti sọ tọkàn wọn

a Bí àpẹẹrẹ, ṣé ìdí tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n ń kó àwọn ọmọ sí àbí wọ́n ń jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó máa kọ́ wọ́n lẹ́kọ̀ọ́ táá sì dá wọn lára yá?