Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ta Ni Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Náà àti Lásárù?

Ta Ni Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Náà àti Lásárù?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà àti Lásárù nínú ìtàn kan tó sọ. (Lúùkù 16:19-31) Àwọn ọkùnrin inú ìtàn Jésù yìí dúró fún àwùjọ àwọn èèyàn méjì: (1) àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù agbéraga nígbà ayé Jésù àti (2) àwọn olóòótọ́ ẹni rírẹlẹ̀ tí wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Kí ni Jésù sọ nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà àti Lásárù?

 Nínú Lúùkù orí 16, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin méjì kan tí àyípadà ńlá ṣẹlẹ̀ sí ipò tí wọ́n wà.

 Bí Jésù ṣe sọ ìtàn náà rèé: Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ kan wà, ọkùnrin aláìní kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lásárù máa ń wà ní ẹnu ọ̀nà ilé ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, kó lè jẹ ohunkóhun tó bá já bọ́ látorí tábìlì rẹ̀. Nígbà tó yá, Lásárù kú, àwọn áńgẹ́lì sì gbé e lọ sọ́dọ̀ Ábúráhámù. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà kú, wọ́n sì sin ín. Jésù sọ ìtàn yẹn bíi pé àwọn ọkùnrin méjèèjì ṣì mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti kú. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ń joró gidigidi nínú iná tó ń jó lala, ó wá ń bẹ Ábúráhámù kó sọ pé kí Lásárù fi ìka kán omi sí òun lẹ́nu. Ábúráhámù ò dáhùn, ó sì sọ fún ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà pé ipò àwọn méjèèjì ti yí pa dà àti pé ọ̀gbun ńlá kan ti wà láàárín wọn tí ò lè jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọdá sódì kejì.

 Ṣé ìtàn yìí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́?

 Rárá o. Jésù ló sọ àkàwé yìí láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Àwọn ọ̀mọ̀wé náà jẹ́rìí sí i pé àkàwé ni ìtàn tí Jésù sọ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìsọ̀rí kan nínú Bíbélì Luther ti ọdún 1912 sọ pé àkàwé ni ìtàn yìí. Bákan náà, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kan nínú Bíbélì Catholic Jerusalem Bible sọ pé “àkàwé tá a sọ bí ìtàn lọ̀rọ̀ yìí, àwọn orúkọ tí Jésù sì mẹ́nu bà kì í ṣe táwọn tó gbé láyé.”

 Ṣé ohun tí Jésù fi ń kọ́ni ni pé téèyàn bá kú, á lọ máa gbé níbòmíì? Àbí ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn kan máa lọ joró ní ọ̀run àpáàdì lẹ́yìn tí wọ́n bá kú àti pé Ábúráhámù àti Lásárù wà lọ́run? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.

 Bí àpẹẹrẹ:

  •   Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ń jorí nínú iná, ṣé iná náà kò ní lá omi tó wà ní ìka Lásárù?

  •   Ká tiẹ̀ sọ pé iná náà ò lá omi náà, ṣé ẹ̀kán omi kan lè mú ìtura tó wà pẹ́ títí wá fún ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó ń joró nínú iná gidi kan?

  •   Jésù sọ ní kedere pé títí di àkókò yẹn, kò sẹ́ni tó tíì lọ sọ́run. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé a lè sọ pé Ábúráhámù wà lọ́run lákòókò yẹn?​—Jòhánù 3:13.

 Ṣé ìtàn yìí fi hàn pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì?

 Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn yìí kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, àwọn kan sọ pé ìtàn náà fi hàn pé àwọn ẹni rere máa ń lọ sọ́run, àwọn èèyàn burúkú sì máa ń lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì. a

 Ṣé èrò yẹn tọ̀nà? Rárá.

 Ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì ta ko ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò fi kọ́ni pé gbogbo àwọn èèyàn rere tó kú máa lọ gbádùn lọ́run tàbí pé àwọn èèyàn burúkú ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn máa kú, àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”​—Oníwàásù 9:5.

 Kí ni ìtàn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà àti Lásárù túmọ̀ sí?

 Ìtàn yẹn jẹ́ ká rí i pé ipò àwùjọ àwọn èèyàn máa yí pa dà pátápátá.

 Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù “tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó.” (Lúùkù 16:14) Wọ́n tẹ́tẹ́ sílẹ̀ bí Jésu ṣe ń kọ́ni, àmọ́ wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn èèyàn tí ò lẹ́nu láwùjọ.​—Jòhánù 7:49.

 Lásárù ṣàpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí ò lẹ́nu láwùjọ. Àwọn yìí fara mọ́ ẹ̀kọ́ Jésù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn.

 Ipò àwùjọ méjèèjì yí pa dà pátápátá.

  •   Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ronú pé àwọn ni Ọlọ́run ń fojúure hàn sí. Àmọ́ wọ́n kú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí Ọlọ́run pa wọ́n tì, tí kò sì tẹ́wọ́ gba ọ̀nà ìjọsìn wọn mọ́ torí pé wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Jésù. Bákan náà, ṣe ni ohun tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń wàásù dà bí ìgbà tí wọ́n ń dá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn lóró.​—Mátíù 23:29, 30; Ìṣe 5:29-33.

  •   Àwọn tí ò lẹ́nu láwùjọ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti tẹ́ńbẹ́lú tẹ́lẹ̀ ni Ọlọ́run wá yọ́nú sí báyìí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn fara mọ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni, ẹ̀kọ́ náà sì ṣe wọ́n láǹfààní. Ìyẹn mú kí wọ́n láǹfààní láti rí ojúure Ọlọ́run títí láé.​—Jòhánù 17:3.

a Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan pe ibi tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà lọ lẹ́yìn tó kú ní “ọ̀run àpáàdì.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò nínú Lúùkù 16:23 ni Hédíìsì, ohun tó sì túmọ̀ sí ni isà òkú gbogbo aráyé.