Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Nọ́ńbà Náà 666 Túmọ̀ Sí?

Kí Ni Nọ́ńbà Náà 666 Túmọ̀ Sí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ pé 666 ni orúkọ tàbí nọ́ńbà orúkọ ẹranko ẹhànnà tó jáde wá láti inú òkun, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (Ìṣípayá 13:1, 17, 18) Ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún ètò ìṣèlú àgbáyé tó ń ṣàkóso lórí “gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.” (Ìṣípayá 13:7) Orúkọ náà 666 fi hàn pé, ìjọba ayé yìí ti kùnà pátápátá lójú Ọlọ́run. Lọ́nà wo?

Kì í ṣe àkọlé lásán. Orúkọ tí Ọlọ́run bá sọ èèyàn tàbí nǹkan máa ń ní ìtumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa sọ Ábúrámù di “baba ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.” Torí náà, ó yí orúkọ Ábúrámù, èyí tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Gbé Bàbá Ga” pá dà di Ábúráhámù tó túmọ̀ sí “Bàbá Ogunlọ́gọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:5) Lọ́nà kan náà, orúkọ tàbí nọ́ńbà náà 666 tí Ọlọ́run fún ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún ohun tí Ọlọ́run rí pé ó jẹ́ ìwà àti ìṣe rẹ̀.

Nọ́ńbà náà, ẹẹ́fà tọ́ka sí àìpé. Bíbélì sábà máa ń lo nọ́ńbà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, eéje dúró fún ohun tó pé pérépéré tàbí ohun pípé lójú Ọlọ́run. Àmọ́, ẹẹ́fà dúró fún ohun tí kò pé tàbí ohun tó lábùkù lójú Ọlọ́run torí pé ó fi oókan dín sí eéje, Bíbélì sì máa ń lò ó fún àwọn ọ̀tá Ọlọ́run.​—1 Kíróníkà 20:6; Dáníẹ́lì 3:1.

Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta túmọ̀ sí ìtẹnumọ́. Nígbà míì, Bíbélì máa ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa sísọ ọ́ lẹ́ẹ̀mẹta. (Ìṣípayá 4:8; 8:13) Torí náà, ẹẹ́fà lẹ́ẹ̀mẹta, ìyẹn 666 ń tẹnu mọ́ kókó náà pé ìjọba ẹ̀dá èèyàn ti kùnà pátápátá lójú Ọlọ́run. Kò ṣe é ṣe fún wọn láti mú kí àlàáfíà àti ààbò pípẹ́ títí wà fáwọn èèyàn torí pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é.

Àmì ẹranko ẹhànnà náà

 Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn gba “àmì ẹranko ẹhànnà náà” torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé e “pẹ̀lú ìkansáárá,” débi pé wọ́n tiẹ̀ jọ́sìn rẹ̀. (Ìṣípayá 13:3, 4; 16:2) Lọ́nà wo? Wọ́n ń bọlá fún orílẹ̀-èdè wọn, àwọn àmì rẹ̀, àti agbára ogun jíjà rẹ̀ bíi pé wọ́n ń sìn wọ́n. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi ló dára jù ti gbòde kan lóde òní, ó tiẹ̀ ti di ẹ̀sìn táwọn èèyàn ń ṣe báyìí.” a

 Báwo ni àmì ẹranko ẹhànnà yìí ṣe lè wà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹnì kan tàbí iwájú orí rẹ̀? (Ìṣípayá 13:16) Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sọ fún wọn nípa àwọn àṣẹ rẹ̀ pé: “Kí ẹ sì dè wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ yín, wọn yóò sì jẹ́ ọ̀já ìgbàjú láàárín àwọn ojú yín.” (Diutarónómì 11:18) Èyí ò túmọ̀ sí pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sàmì sí ọwọ́ àti iwájú orí wọn, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe àti ìrònú wọn. Lọ́nà kan náà, 666 kì í ṣe àmì tí wọ́n fín sára ẹnì kan, àmọ́ ṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó jẹ́ kí ètò ìṣèlú máa darí ìrònú àti ìwà wọn. Àwọn tó gba àmì ẹranko ẹhànnà náà ń sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọ́run.​—Ìṣípayá 14:9, 10; 19:19-​21.

a Tún wo ìwé Nationalism in a Global Era, ojú ìwé 134, àti ìwé Nationalism and the Mind: Essays on Modern Culture, ojú ìwé 94.