Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ẹni Gidi Ni Ọlọ́run?

Ṣé Ẹni Gidi Ni Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Agbára tí Ọlọ́run ní kò láfiwé. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe dá àìmọye ìràwọ̀, ó sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni [Ọlọ́run] fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:25, 26.

 Àmọ́, ẹni gidi ni Ọlọ́run, kì í ṣe agbára àìrí kan. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ń mọ nǹkan lára, ó láwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn ohun tó kórìíra. (Sáàmù 11:5; Jòhánù 3:16) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí a bá ṣe lè mú kí inú Ọlọ́run dùn tàbí kí inú rẹ̀ bà jẹ́.—Sáàmù 78:40, 41.