Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Bíbélì Nípa Ìgbésí Ayé Jésù Péye?

Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Bíbélì Nípa Ìgbésí Ayé Jésù Péye?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Lúùkù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ nípa àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé Jésù tó kọ, ó ní: “Mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.”—Lúùkù 1:3.

 Àwọn kan sọ pé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin àwọn èèyàn kan ti ṣe àyípadà àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé Jésù tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn àwọn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Àmọ́, wọ́n rí àjákù ìwé Ìhìn Rere Jòhánù ní Íjíbítì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún. Wọ́n ń pè é ní Papyrus Rylands 457 (P52), wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé ìkówèésí John Rylands Library, ní Manchester, nílẹ̀ England. Ohun tó wà nínú Jòhánù 18:31-33, 37, 38 nínú àwọn Bíbélì òde òní ló wà nínú rẹ̀.

 Òun ni àjákù ìwé àfọwọ́kọ ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó pẹ́ jù lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé wọ́n ṣe ẹ̀dà rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 125 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ inú àjákù náà fẹ́rẹ̀ẹ́ bá gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ lẹ́yìn rẹ̀ mu tán.