Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Látinú Àpamọ́ Wa

Wàá rí ìtàn nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní.

Ìtàn Wa

À Ń Wàásù Ìhìn Rere Lórí Rédíò Àti Tẹlifíṣọ̀n

Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lo iléeṣẹ́ rédíò WBBR láti wàásù ìhìn rere?

“Akoko Ta A Moyi Ju Lo”

Iwe iroyin Zion’s Watch Tower so pe Iranti Iku Kristi je “akoko ta a moyi ju lo,” o si ro awon to n ka a pe ki won se iranti yii. Bawo ni won se n se Iranti Iku Kristi nigba yen lohun un?

‘Ìkórè Ṣì Pọ̀’

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní 760,000 ló ń wàásù ìhìn rere náà ní orílẹ̀-èdè Brazil. Báwo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkórè ní Amẹ́ríkà Gúúsù?

O Ri I Pe Ife Lo Mu Ki Nnkan Wa Letoleto Nile Ijeun Naa

To ba je pe láti awon odun 1990 si 1999 tabi leyin igba naa lo to bere si i lo si apejo agbegbe awa Elerii Jehofa, a wu e lori láti ko nipa awon ohun ta a maa n se lawon apejo ta a ti se ni opo odun seyin.

Bí Iṣẹ́ Fífúnrúgbìn Ìjọba Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórílẹ̀-Èdè Pọ́túgà

Àwọn ìṣòro wo làwọn tó kọ́kọ́ wàásù níbẹ̀ borí?

1870 to 1918

Àsọyé fún Gbogbo Èèyàn Mú Kí Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀ ní Ireland

Kí ló jẹ́ kí Arákùnrin C. T. Russell gbà pé pápá “tó ti tó kórè” ni Ireland?

Sinimá Tó Dá Lórí Ìṣẹ̀dá Ti Pé Ọgọ́rùn-ún Ọdún Báyìí

Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún tá a kọ́kọ́ gbé sinimá “Photo-Drama of Creation” jáde, káwọn èèyàn lè gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” Mú Kí Ọ̀pọ̀ Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Àwọn tó wà láwọn abúlé oko, kódà láwọn ibi tí kò sí iná mànàmáná lè wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí kò gùn tó “Photo-Drama of Creation” yìí.

“Iṣẹ́ Ìwàásù Mi Ń Sèso Rere, Ó sì Ń Fògo fún Jèhófà”

Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò lóye àwọn ìlànà Bíbélì nípa ogun dáadáa nígbà ogun àgbáyé kìíní, síbẹ̀ ìwà wọn àti ìṣesí wọn sèso rere.

Wọ́n Dúró Ṣinṣin ní “Wákàtí Ìdánwò”

Kà nípa bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rí sí àwọn ará wa lọ́dún 1914 nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, nítorí pé wọ́n ò dá sí ọ̀ràn ogun.

1919 to 1930

“Àwọn Tá A Fa Iṣẹ́ Náà Lé Lọ́wọ́”

Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919 jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan tó máa kárí ayé.

“Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”

Lẹ́yìn àpéjọ tó wáyé lọ́dún 1922, báwo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni náà pé kí wọ́n “fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀”?

‘Ìwàásù Tí Wọn Kò Gbọ́ Irú Rẹ̀ Rí’

Nígbà tó fi máa di ọdún 1926, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táà ń pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ti ní ilé-iṣẹ́ rédíò tiwọn ní ìlú mẹ́rin ní Kánádà.

“Ohun Mánigbàgbé” Tó Bọ́ Sákòókò

Wo bí sinimá túntun tó ń jẹ́ “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá” ṣe ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá ní Jámánì lọ́wọ́ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

“Jèhófà Mú Yín Wá sí Ilẹ̀ Faransé Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́”

Ìwé àdéhùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Poland àti ti ilẹ̀ Faransé ti ọwọ́ bọ̀ ní ọdún 1919 ní àbájáde tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀.

“Mò Ń Gbé Ilé Mi Kiri bí Ìgbín”

Níparí ọdún 1929, ọrọ̀ ajé dojú rú kárí ayé. Báwo làwọn oníwàásù alákòókò kíkún ṣe gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà yánpọnyánrin yẹn?

1931 to Present

A Wà Níṣọ̀kan Lórílẹ̀-Èdè Táwọn Èèyàn Ti Kẹ̀yìn Síra

Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é tí wọ́n fi wà níṣọ̀kan lákòókò kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà? Kí làwa náà lè rí kọ́ látinú ohun tí wọ́n ṣe?

“Ohunkóhun Ò Gbọ́dọ̀ Dí Yín Lọ́wọ́!”

Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó wà nílẹ̀ Faransé láwọn ọdún 1930 sí ọdún 1939 fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ní ìtara àti ìfaradà.

“Kò Sí Ọ̀nà Tó Burú Jù Tàbí Jìn Jù”

Níparí àwọn ọdún 1920 sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, àwọn aṣáájú-ọ̀nà fi ìtara wọn hàn nígbà tí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ìgbèríko Ọsirélíà.

“Ìgbà Wo La Tún Máa Ṣe Àpéjọ Mí ì?”

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àpéjọ àgbègbè kékeré tí wọ́n ṣe ní Mexico City lọ́dún 1932?

Inú Ọba Dùn!

Kà nípa bí ọba kan lórílẹ̀-èdè Swaziland ṣe fi hàn pé òun mọyì ẹ̀kọ Bíbélì.

Ọkọ̀ Ojú Omi Lightbearer Tan Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Dé Ilẹ̀ Éṣíà

Láìka àtakò sí, àwọn kéréje tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi Lightbearer fi ìgboyà fún irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó láwọn èrò tó pọ̀ gan-an tí wọ́n ń gbé ibẹ̀.

“Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́, Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Tó Wà Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì!!”

Iye àwọn èèyàn tó wá sínú ètò ọlọ́run nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín ọdún mẹ́wàá kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan! Kí lohun tó wá mú káwọn èèyàn máa rọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run?

Ṣé Èèyàn Àlàáfíà àti Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New Zealand?

Ní àwọn ọdún 1940, kí nìdí tí wọ́n fi ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ewu fún àwọn ará ìlú?

Ohun Tó Dáa Jù Ni Wọ́n Fi Ránṣẹ́

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn ará wọn ní Jámánì lọ́wọ́ gbàrà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí?

À Ń Ran Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́wọ́ Láti Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

Àwọn aláṣẹ ní onírúurú orílẹ̀-èdè ti gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe láti mú káwọn èèyàn mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà.