Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

HÅKAN DAVIDSSON | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Kọ́wọ́ Ti Iṣẹ́ Tó Ń Mú Kí Òtítọ́ Bíbélì Gbilẹ̀

A Kọ́wọ́ Ti Iṣẹ́ Tó Ń Mú Kí Òtítọ́ Bíbélì Gbilẹ̀

 Orílẹ̀-èdè Sweden ni wọ́n bí mi sí, ibẹ̀ náà ni mo dàgbà sí. Mi ò gbà pé Ọlọ́run wà nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Torí náà nígbà tí bàbá mi, ìyá mi àti àbúrò mi obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ohun tí wọ́n ń ṣe ò tiẹ̀ wù mí rárá.

 Gbogbo ìgbà tí bàbá mi bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n máa ń pè mí pé kí n dara pọ̀ mọ́ wọn, àmọ́ mi ò rí tiwọn rò. Lọ́jọ́ kan, mo pinnu láti jókòó síbi tí wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹnu yà mí gan-an nígbà tí mo rí bí Bíbélì ṣe bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo wá rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́. Mo tún rí i pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kọ́ni lóhun tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n sì ń fi ohun ti Bíbélì sọ sílò nígbèésí ayé wọn. Inú mi dùn gan-an pé ọjọ́ kan náà lèmi àti bàbá mi ṣèrìbọmi lọ́dún 1970. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni màmá mi àtàwọn àbúrò mi méjì ṣèrìbọmi.

 Ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ mi ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ká gbafẹ́, ká sì lọ sóde àríyá ló jẹ wọ́n lógún. Kí n má parọ́ irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ wu èmi náà, torí pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) péré ni mí nígbà yẹn. Àmọ́ mo kíyè sí i pé gbogbo ìgbà ni inú àwọn tí wọ́n ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ mi máa ń dùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe, ìyẹn ló jẹ́ kó wù mí láti dara pọ̀ mọ́ wọn. Mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21).

Èmi àti bàbá mi (lápá òsì) jọ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà

 Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, mo gbádùn ẹ̀ gan-an débi pé ó dùn mí pé mi ò tètè bẹ̀rẹ̀. Gbogbo ìgbà tá a bá ti lọ wàásù ní ibùdó ọkọ̀ òkun tó wà ní Göteborg ni inú mi máa ń dùn, torí mo máa ń wàásù fún àwọn awakọ̀ òkun tí wọ́n ń sọ onírúurú èdè.

 Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún (50) báyìí tí mo ti ń ran àwọn tó ń sọ onírúurú èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ìhìn rere lédè wọn. Ẹ jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún yín.

À Ń Fi MEPS Ṣiṣẹ́

 Kí n lè máa rówó gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mò ń ṣe, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ìtẹ̀wé fún ọjọ́ mélòó kan lọ́sẹ̀. Lákòókò yẹn, ìtẹ̀síwájú ti bá iṣẹ́ ìtẹ̀wé gan-an. Dípò ká máa lo àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tí wọ́n tò pọ̀, a máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn àwòrán tí wọ́n fi fọ́tò yà. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi kọ̀ǹpútà to ọ̀rọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè gbé e sórí àwo tí wọ́n fi ń tẹ̀wé.

Lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa

 Lọ́dún 1980, mo fẹ́ Helene, aṣáájú-ọ̀nà bíi tèmi lòun náà, ó sì fẹ́ràn kó máa wàásù fún onírúurú èèyàn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé. Ó tún fẹ́ràn kó máa kọ́ àwọn àṣà wọn. Ohun tó wù wá ni pé ká lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ká sì di míṣọ́nnárì.

 Àmọ́ torí pé mo ti ṣiṣẹ́ nílé ìtẹ̀wé rí, wọ́n ní kí èmi àti ìyàwó mi lọ máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Sweden. Ètò Ọlọ́run fẹ́ lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti mú kí ọ̀nà tá à ń gbà tẹ̀wé túbọ̀ rọrùn kó sì yá. Torí náà lọ́dún 1983, wọ́n ní ká lọ sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill ní New York kí wọ́n lè dá wa lẹ́kọ̀ọ́ lórí Multilanguage Electronic Phototypsetting System (MEPS) a táwọn ará ń ṣiṣẹ́ lé lọ́wọ́.

À ń ṣètò bá a ṣe máa ṣe MEPS fún orílẹ̀-èdè Hong Kong, Mexico, Nàìjíríà, àti Sípéènì

 Ètò kọ̀ǹpútà kan ni MEPS, ó máa ń jẹ́ ká lè tẹ oríṣiríṣi álífábẹ́ẹ̀tì lónírúurú ọ̀nà, kó sì tún ní àwọn àwòrán lójú ìwé kan náà. Iṣẹ́ tiwa ni pé, ká ṣètò àwọn álífábẹ́ẹ̀tì míì sínú MEPS ìyẹn lá jẹ́ ká lè tẹ àwọn ìwé wa lédè tó pọ̀ sí i. Ní báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ àwọn ìwé tó ń kéde ìhìn rere ni èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ!

 Nígbà tó yá, wọ́n ní kí èmi àti ìyàwó mi lọ sí Éṣíà ká lè wo bá a ṣe máa fi àwọn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ kún àwọn èdè tó wà lórí MEPS. Inú wa dùn gan-an láti lọ síbẹ̀, a sì fayọ̀ tẹ́wọ́ gba àǹfààní náà!

Àṣà Ìbílẹ̀ Tó Yàtọ̀ sí Tiwa Pátápátá

 Ní 1986, èmi àti ìyàwó mi gúnlẹ̀ sí Bombay tí wọ́n ń pè ní Mumbai báyìí ní orílẹ̀-èdè Íńdíà. Bá a ṣe débẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ò yé wa torí pé àwọn ohun tá a bá níbẹ̀ ṣàjèjì sí wa. Àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ pátápátá sí tiwa. Kódà ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tá a lò níbẹ̀, ṣe ló ń ṣe wá bíi pé ká pa dà sílé.

 Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan yẹn, a sọ fún ara wa pé: ‘Ṣebí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló wù wá ṣe tẹ́lẹ̀. Ní báyìí tá a ti ń sìn lórílẹ̀-èdè míì, ṣé a máa wá pa dà sílé ni? Àfi ká yá a sọ ibí dilé.’

 Torí náà, dípò ká pa dà sílé, a pinnu pé àá kọ́ àṣà ìbílẹ̀ wọn kára wa lè mọlé. Ìyẹn jẹ́ ká túbọ̀ gbádùn orílẹ̀-èdè Íńdíà. Kódà, a kọ́ méjì lára èdè wọn ìyẹn Gujarati àti Punjabi.

A Lọ sí Myanmar

A wọ aṣọ ìbílẹ̀ tí wọ́n ń wọ̀ ní Myanmar lọ sílé ìpàdé

 Ní 1988, wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Myanmar tó wà láàárín orílẹ̀-èdè China, Íńdíà, àti Thailand. Nǹkan ò fara rọ ní Myanmar kódà àwọn ológun ló ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀nà ìgbà kọ̀wé wọn ò tíì sí lórí MEPS, kò sì sí ètò kọ̀ǹpútà míì tá a lè lò. Torí náà, iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ ṣe ni pé, a ṣètò àwọn álífábẹ́ẹ̀tì wọn, a sì kó wọn lọ sí Wallkill kí wọ́n lè gbé e sórí MEPS.

 Ní pápákọ̀ òfúrufú, ìyàwó mi kó àwọn álífábẹ́ẹ̀tì náà sínú báàgì tó gbé sọ́wọ́. Torí pé nǹkan ò fara rọ lásìkò yẹn táwọn ọlọ́pàá ibodè bá ká àwọn ìwé tá a ṣe ni èdè Myanmar mọ́ wa lọ́wọ́, ṣe ni wọ́n máa mú wa. Nígbà tí wọ́n ń yẹ ara ìyàwó mi wò, ṣe ló káwọ́ sókè tó sì na báàgì náà sókè. Kò sẹ́ni tó kíyè sí báàgì náà rárá!

MEPS jẹ́ kí àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ túbọ̀ dáa

 Yàtọ̀ sí àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, ètò Ọlọ́run tún fún àwọn atúmọ̀ èdè Myanmar ní ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, wọ́n sì tún kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe lo MEPS. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn atúmọ̀ èdè náà ni ò rí kọ̀ǹpútà rí, wọ́n lọ́kàn tó dáa, ó sì wù wọ́n láti kọ́ àwọn nǹkan tuntun. Bó ṣe di pé wọn ò lo ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ mọ́ nìyẹn. Ìyẹn wá jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń tẹ̀wé túbọ̀ rọrùn, ó sì jẹ́ káwọn ìwé tá à ń tẹ̀ túbọ̀ dáa.

A Lọ sí Nepal

 Ní 1991, wọ́n ní kí èmi àti ìyàwó mi máa lọ sí orílẹ̀-èdè Nepal, tó wà ni apá gúúsù àwọn òkè Himalaya. Lásìkò yẹn, ìjọ kan ṣoṣo ló wà ní orílẹ̀-èdè náà, díẹ̀ nínú àwọn ìwé wa ni wọ́n sì tú sí èdè Nepali.

 Kò pẹ́ sígbà yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí í tú àwọn ìwé wa sí èdè Nepali. Ní báyìí, àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ló wà ni ìjọ tó lé ní ogójì (40) ní Nepal. Àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún méje ààbọ̀ lọ (7,500) ló wá sí Ìrántí Ikú Jésù lọ́dún 2022!

A Tú Ìwé Kan sí Èdè Lahu

 Láwọn ọdún 1990, àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ń gbé nílùú Chiang Mai, lórílẹ̀-èdè Thailand bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn ẹ̀yà Lahu tó ń gbé lórí òkè. Àwọn tó ń gbé nítòsí ibodè China, Laos, Myanmar, Thailand, àti Vietnam ló ń sọ èdè Lahu. Àmọ́ a ò tíì tú èyíkéyìí lára àwọn ìwé wa sí èdè yẹn.

 Ọ̀dọ́kùnrin kan tí àwọn míṣọ́nnárì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tú ìwé “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun” láti èdè Thai sí èdè Lahu. Òun àtàwọn ará abúlé náà wá dáwó, wọn sì fi owó náà àti ìwé tó tú ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Nínú lẹ́tà tí wọ́n kọ, wọ́n ní àwọn fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Lahu gbọ́ òtítọ́ táwọn ti kọ́ nínú ìwé yẹn.

 Nígbà tó yá, èmi àti ìyàwó mi láǹfààní láti kọ́ àwọn atúmọ̀ èdè Lahu bí wọ́n á ṣe lo MEPS. Arákùnrin kan wà lára àwọn atúmọ̀ èdè tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Chiang Mai. Ó yà mí lẹ́nu gan-an láti mọ̀ pé òun ni ọ̀dọ́kùnrin tó túmọ̀ ìwé “Sawo O!” sí èdè Lahu!

 Ní 1995, èmi àti ìyàwó mi pa dà sí Íńdíà ká lè fún àwọn atúmọ̀ èdè tó wà níbẹ̀ ní àwọn ètò MEPS tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ wọn. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní Íńdíà ló láwọn ìwé tó pọ̀ tó lédè wọn káwọn èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì ṣèrìbọmi.

A Ò Kábàámọ̀ Ohun Tá A Fayé Wa Ṣe

 Èmi àti Helene ìyàwó mi ti ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Britain láti ọdún 1999. A sì ń bá ẹ̀ka tó ń ṣètò MEPS ní orílé-iṣẹ́ wa ṣiṣẹ́. Inú wa dùn gan-an pé à ń wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Gujarati àti Punjabi ní London. Ìgbàkigbà tá a bá ti rí èdè tuntun lórí jw.org, ó máa ń wù wá pé ká wàásù fáwọn tó ń sọ èdè náà lágbègbè wa.

 Inú mi dùn gan-an pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni mo fayé mi ṣe dípò kí n máa “jayé kiri.” Nígbàkigbà témi àti ìyàwó mi bá ronú nípa ohun tá a fayé wa ṣe, a kì í kábàámọ̀ pé Jèhófà la fayé wa sìn. A ti lọ sí orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgbọ̀n (30), a sì ti fojú ara wa rí bí Jèhófà ṣe ń jẹ́ kí ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n!​—Ìfihàn 14:6.

a Multilanguage Electronic Publishing System là ń pè é báyìí. Òun la sì ń lò láti gbé àwọn ìwé wa sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì