“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”

Ìwé yìí sọ nípa bí wọ́n ṣe dá ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sílẹ̀ àti bó ṣe kàn wá lónìí.

Àwòrán Ilẹ̀

Àwòrán ilẹ̀ tó jẹ́ ká mọ ibi tí wọ́n sábà máa ń pè ní Ilẹ̀ Mímọ́ lóde òní àtàwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù gbà nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run”?

ORÍ 1

“Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ lónìí?

ORÍ 2

“Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”

Báwo ni Jésù ṣe múra àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

ORÍ 3

Wọ́n “Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́”

Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀?

ORÍ 4

‘Àwọn Èèyàn Tí Ò Kàwé àti Gbáàtúù’

Àwọn àpọ́sítélì fìgboyà wàásù, Jèhófà sì mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí.

ORÍ 5

“A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Alákòóso Dípò Èèyàn”

Ohun tawon apositeli yen se je apeere to daa to si ye kawa Kristeni tooto maa te le.

ORÍ 6

Sítéfánù “Kún fún Oore Ọlọ́run àti Agbára”

Kí la lè rí kọ́ látinú bí Sítéfánù ṣe fìgboyà jẹ́rìí níwájú ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù?

ORÍ 7

Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”

Fílípì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa lẹ́nu iṣẹ́ ajíhìnrere.

ORÍ 8

Ìjọ “Wọnú Àkókò Àlàáfíà”

Sọ́ọ̀lù alátakò tó burú gan-an di òjíṣẹ́ onítara.

ORÍ 9

“Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú”

Àwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́.

ORÍ 10

“Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀”

Áńgẹ́lì tú Pétérù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ìhìn rere sì ń gbilẹ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni.

ORÍ 11

Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”

Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà táwọn èèyàn ta kò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

ORÍ 12

Wọ́n “Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípasẹ̀ Àṣẹ Jèhófà”

Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n ní ìforítì, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bá onírúurú èèyàn mu.

ORÍ 13

‘Lẹ́yìn Tí Wọ́n Jiyàn Díẹ̀’

Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lọ síwájú ìgbìmọ̀ olùdarí.

ORÍ 14

“A Ti Fìmọ̀ Ṣọ̀kan”

Wo bí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe yanjú ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ àti bí ìpinnu tí wọ́n ṣe ṣe jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.

ORÍ 15

Pọ́ọ̀lù “Ń Fún Àwọn Ìjọ Lókun”

Àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.

ORI 16

“Sọdá Wá sí Makedóníà”

Wọ́n rí ìbùkún gbà torí pé wọ́n gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wọn, wọ́n sì ń láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wọn.

ORÍ 17

‘Ó Bá Wọn Fèròwérò Látinú Ìwé Mímọ́’

Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà àti Bèróà.

ORÍ 18

Ẹ Wá Ọlọ́run, Kẹ́ Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ níbi tí èrò ẹ̀ àti tàwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ ti jọra, báwo nìyẹn ṣe mú kó ṣée ṣe fún un láti wàásù?

ORÍ 19

“Máa Sọ̀rọ̀ Nìṣó, Má sì Dákẹ́”

Kí la rí kọ́ látinú àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ṣe ní ìlú Kọ́ríńtì táá jẹ́ ká lè máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run?

ORÍ 20

“Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀ Nìṣó, Ó sì Ń Borí” Lójú Àtakò

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Àpólò àti Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú.

ORÍ 21

“Ọrùn Mi Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀jẹ̀ Gbogbo Èèyàn”

Pọ́ọ̀lù fìtara wàásù, ó sì ń fún àwọn alàgbà nímọ̀ràn.

ORÍ 22

“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”

Pọ́ọ̀lù múra tán láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù.

ORÍ 23

“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”

Pọ́ọ̀lù gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀ níwájú àwọn jàǹdùkú tínú ń bí àti níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn.

ORÍ 24

“Mọ́kàn Le!”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á, ó sì gbẹ̀jà ara ẹ̀ níwájú Gómìnà Fẹ́líìsì.

ORÍ 25

“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”

Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè gbèjà ìhìn rere.

ORÍ 26

“Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”

Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára àti pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nígbà tí ọkọ̀ tó wọ̀ rì.

ORÍ 27

“Jẹ́rìí Kúnnákúnná”

Wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, síbẹ̀ ó ń bá a lọ láti máa wàásù.

ORÍ 28

“Títí Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a lọ láti máa ṣe iṣẹ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

Atọ́ka Àwòrán

Àwọn àwòrán tó ṣe kókó nínú Ìwé yìí.