Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n kọ orúkọ Tátánù sí etí wàláà yì

Ẹ̀rí Mí ì Tún Rèé

Ẹ̀rí Mí ì Tún Rèé

Ǹjẹ́ àwọn awalẹ̀pìtàn rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì? Lọ́dún 2014, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review béèrè ìbéèrè yìí: “Mélòó nínú àwọn èèyàn tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dárúkọ wọn làwọn awalẹ̀pitàn ti jẹ́rìí sí pé wọ́n wà lóòótọ́?” Ìdáhùn wọn ni pé: “Ó kéré tán, a rí àádọ́ta!” Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ kò sí nínú àkọsílẹ̀ náà ni Táténáì. Ta ni ọkùnrin yìí? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.

Ara Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tó fẹ̀ lọ salalu ni Jerúsálẹ́mù wà tẹ́lẹ̀. Ìlú yìí wà ní àgbègbè ibi tí àwọn ará Páṣíà ń pè ní Òdì-kejì-Odò, ìyẹn ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yúfírétì. Lẹ́yìn táwọn ará Páṣíà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, wọ́n dá àwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn sílẹ̀, wọ́n sì fún wọn láṣẹ láti tún tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹmù kọ́. (Ẹ́sírà 1:1-4) Àmọ́ àwọn ọ̀tá àwọn Júù kò fẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Páṣíà. (Ẹ́sírà 4:4-16) Nígbà ìṣàkóso Dáríúsì Kìíní (ọdún 522 sí 486 ṣáájú Sànmánì Kristẹni), aṣojú ìjọba Páṣíà kan tó ń jẹ́ Táténáì kó àwọn kan sòdí láti wá ṣe ìwádìí nípa iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Bíbélì pè é ní “gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò.”Ẹ́sírà 5:3-7.

Wọ́n rí wàláà kan tí orúkọ Táténáì wà lára rẹ̀ nínú ibi tá a lè pè ní àpamọ́ ìdílé wọn. Wàláà náà sọ nípa ilérí tẹ́nì kan ṣe lọ́dún 502 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ogún ọdún ìṣàkóso Dáríúsì Kìíní. Wàláà náà sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ ìbátan Táténáì. Ó ní ìránṣẹ́ “Tátánù, gómìnà tó wà ní Òdì-kejì-Odò,” jẹ́rìí sí okòwò kan tó wáyé nígbà yẹn. Tátánù yìí náà ni Táténáì tí Ìwé Ẹ́sírà nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ipa wo ni ọkùnrin yìí kó? Lọ́dún 535 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì Ńlá pín àwọn ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí sí ẹkùn-ìpínlẹ̀, ó pe ọ̀kan lára wọn ní Bábílónì àti Òdì-kejì-Odò. Nígbà tó yá, wọ́n pín ẹkùn-ìpínlẹ̀ náà sí méjì, wọ́n sì pe ọ̀kan lára rẹ̀ ní Òdì-kejì-Odò. Lára àwọn ìlú tó wà níbẹ̀ ni Koele ti Síríà, Fòníṣíà, Samáríà àti Júúdà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ Damásíkù ni olú-ìlú ẹkùn-ìpínlẹ̀ yìí. Táténáì ṣàkóso àgbègbè yìí láti nǹkan bí ọdún 520 sí 502 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Lẹ́yìn tí Táténáì rìnrìn-àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣèwádìí ẹ̀sùn ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n fi kan àwọn Júù, ó pa dà wá jábọ̀ fún Dáríúsì pé àwọn Júù sọ pé Kírúsì ló fún àwọn láṣẹ láti tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. Nígbà tí wọ́n wo ibi tí wọ́n ń kó àkọsílẹ̀ sí láààfin, wọ́n rí i pé òótọ́ ni wọ́n sọ. (Ẹ́sírà 5:6, 7, 11-13; 6:1-3) Torí náà, wọ́n pàṣẹ fún Táténáì pé kò gbọ́dọ̀ dí wọn lọ́wọ́, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.Ẹ́sírà 6:6, 7, 13.

Ohun kan ni pé “Táténáì gómìnà tí ó wà ní ìkọjá Odò” kò gbé nǹkan tó gbàfiyèsí gidi kan ṣe. Síbẹ̀, wàá kíyè sí i pé Ìwé Mímọ́ dárúkọ rẹ̀, ó sì tún pè é lórúkọ oyè tó jẹ gangan. Àwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí yìí jẹ́ ẹ̀rí míì tó mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé òótọ́ làwọn ìtàn inú Bíbélì.