Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ A Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn?

Ǹjẹ́ A Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn?

Ǹjẹ́ o ti ka ìtàn kan rí nípa àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn dáadáa, kó o sì máa sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Mi ò lè dàbí wọn láé!’ O lè máa ronú pé, ‘Mo ti ṣe ohun tí kò dáa rí, mi ò sì lè ka ara mi sí olódodo, kódà kì í ṣe gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó tọ́.’

Jóòbù jẹ́ ọkùnrin “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.”—Jóòbù 1:1

Bíbélì sọ pé Jóòbù jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.” (Jóòbù 1:1) Bákan náà, ó pe Lọ́ọ̀tì ní “ọkùnrin olódodo.” (2 Pétérù 2:8) Ó sì sọ nípa Dáfídì pé, ó ṣe “ohun tí ó tọ́” ní ojú Ọlọ́run. (1 Àwọn Ọba 14:8) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé àwọn mẹ́ta yìí. A máa rí i pé (1) wọ́n ṣe àṣìṣe, (2) a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, àti pé (3) àwa èèyàn tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ lè mú inú Ọlọ́run dùn.

WỌ́N ṢE ÀṢÌṢE

“[Ọlọ́run] sì dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè, ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi.”—2 Pétérù 2:7

Jóòbù kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó le koko. Àwọn ìṣòro yìí mú kó ní èrò tí kò tọ́ nípa Ọlọ́run. Ó ronú pé ojú kan náà ni Ọlọ́run fi ń wo ẹni burúkú àti ẹni rere. (Jóòbù 9:20-22) Jóòbù gbà pé olódodo ni òun. Èyí sì mú kí àwọn míì máa wo Jóòbù bí ẹni tí òdodo rẹ̀ ga ju ti Ọlọ́run.—Jóòbù 32:1, 2; 35:1, 2.

Lọ́ọ̀tì lọ́tìkọ̀ láti ṣe ìpinnu tó yẹ lásìkò. Ìṣekúṣe tó bùáyà tó kún ọwọ́ àwọn ará Sódómù àti Gòmórà ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá Lọ́ọ̀tì gan-an. Kódà, Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ìwà burúkú wọn mú “ọkàn òdodo rẹ̀ joró.” (2 Pétérù 2:8) Ọlọ́run wá sọ pé òun máa pa àwọn ìlú náà run, àmọ́ òun á dá Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ sí. O lè máa ronú pé Lọ́ọ̀tì tí ẹ̀dùn ọkàn ti bá ló yẹ kó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa sá kúrò ní ìlú yẹn. Àmọ́ àkókò yẹn gan-an ni Lọ́ọ̀tì wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́ tìkọ̀. Ńṣe ni àwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí òun àti ìdílé rẹ̀ fà wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n sì mú wọn jáde nínú ìlú náà.—Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16.

Dáfídì “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ tọ̀ [Ọlọ́run] lẹ́yìn nípa ṣíṣe kìkì ohun tí ó tọ́ ní ojú [Ọlọ́run].”—1 Àwọn Ọba 14:8

Dáfídì ní tiẹ̀ kò kó ara rẹ̀ níjàánu, ó sì ṣe panṣágà pẹ̀lú aya aláya. Kí Dáfídì lè bo ohun tó ṣe mọ́lẹ̀, ńṣe ló pa ọkọ obìnrin náà. (2 Sámúẹ́lì, orí 11) Bíbélì sọ pé “ohun tí Dáfídì ṣe jẹ́ ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.”—2 Sámúẹ́lì 11:27.

A wá lè rí i báyìí pé Jóòbù, Lọ́ọ̀tì àti Dáfídì ṣe àṣìṣe, kódà àṣìṣe míì burú jáì. Síbẹ̀ a máa rí i pé ó wù wọ́n tọkàntọkàn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Wọ́n kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe, wọ́n sì ṣe tán láti ṣàtúnṣe. Torí náà, Ọlọ́run fi ojú rere wò wọ́n, Bíbélì sì pe àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní olóòótọ́.

KÍ LA LÈ RÍ KỌ́?

Torí pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, a máa ń ṣe àṣìṣe. (Róòmù 3:23) Nígbà tí a bá ṣe àṣìṣe, ó yẹ ká kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, ká sì ṣe tán láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ.

Báwo ni Jóòbù, Lọ́ọ̀tì àti Dáfídì ṣe ṣàtúnṣe tó yẹ? Tọkàntọkàn ni Jóòbù fi jẹ́ olóòótọ́. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run tọ́ ọ sọ́nà, Jóòbù tún èrò rẹ̀ pa, ó sì yíhùn pa dà. (Jóòbù 42:6) Ní ti Lọ́ọ̀tì, irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn ará Sódómù àti Gòmórà ń hù ni òun náà fi ń wò ó. Ṣùgbọ́n bó ṣe ń lọ́ tìkọ̀ nígbà tó yẹ kí ó yára ló jẹ́ ìṣòro rẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó sá kúrò ní ìlú náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ la ìparun ìlú yẹn já. Ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tí àwọn áńgẹ́lì náà fún un, kò sì wẹ̀yìn wo àwọn nǹkan tó fi sílẹ̀ sí ìlú náà. Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá burú jáì, ṣùgbọ́n ó kábàámọ̀, ó sì ronú pìwà dà, ó wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọ́run.—Sáàmù 51.

Ọlọ́run ka àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn sí olódodo torí pé ohun tó ń retí látọ̀dọ̀ àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò pọ̀ jù. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run “mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Nítorí náà, tí Ọlọ́run bá mọ̀ pé a kò lè ṣe ká má ṣàṣìṣe, kí ló ń retí láti ọ̀dọ̀ wa?

Ọlọ́run “mọ ẹ̀dá wa, ò rántí pé ekuru ni wá.” —Sáàmù 103:14

BÁWO NI ÀWA ÈÈYÀN ẸLẸ́ṢẸ̀ ṢE LÈ MÚ INÚ ỌLỌ́RUN DÙN?

Ìmọ̀ràn tí Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn. Ó sọ pé: ‘Ìwọ, Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi, mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré sìn ín.’ (1 Kíróníkà 28:9) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ọkàn-àyà tó pé pérépéré? Ẹni náà máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dọ́kàn, á sì ṣe tán láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ délẹ̀délẹ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé ẹni náà kò ní ṣe àṣìṣe, àmọ́ ó máa ń wu irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa ń ṣe tán láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe múra tán láti ṣègbọràn ló mú kí Jèhófà ka Jóòbù sí “aláìlẹ́bi,” tó mú kó ka Lọ́ọ̀tì sí “olódodo,” tó sì sọ nípa Dáfídì pé ó ṣe “ohun tí ó tọ́” lójú Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàṣìṣe, wọ́n mú inú Ọlọ́run dùn.

Ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ bá pé pérépéré máa ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì máa ń múra tán láti ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀

Torí náà, tí èròkerò bá ń yọ́ wọnú ọkàn rẹ tàbí tó o sọ ohun kan tàbí ṣe ohun kan tó o pa dà wá kábàámọ̀, o lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn tá a ti jíròrò nípa wọn. Ọlọ́run mọ̀ pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a kò lè ṣe ká má ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ó retí pé ká nífẹ̀ẹ́ òun dọ́kàn, ká sì sapá láti jẹ́ onígbọràn. Ó dájú pé tá a bá jẹ́ kí ọkàn wa pé pérépéré lọ́nà yìí, àwa náà máa múnú Ọlọ́run dùn.