Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 3

Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìforítì

Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìforítì

KÍ NI ÌFORÍTÌ?

Ẹni tó bá ní ìforítì kì í jẹ́ kí ìṣòro bo òun mọ́lẹ̀ débi tí kò fi ní lè tẹ̀ síwájú mọ́. Ìwà yìí kì í ṣe ohun tí wọ́n ń bí mọ́ni, ẹnì kan ti gbọ́dọ̀ la ọ̀pọ̀ ìṣòro kọjá ká tó lè sọ pé ó ní ìforítì. A lè fi ọ̀rọ̀ yìí wé ọmọ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, kò sí bí kò ṣe ní máa ṣubú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bákan náà kéèyàn tó lè ṣàṣeyọrí láyé yìí, ó gbọ́dọ̀ la àwọn ìṣòro kọjá.

KÍ NÌDÍ TÍ ÌFORÍTÌ FI ṢE PÀTÀKÌ?

Ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá àwọn ọmọ míì tí wọ́n bá ní ìṣòro tàbí tí nǹkan ò bá rí bí wọ́n ṣe rò tàbí tí àwọn míì bá sọ pé ohun tí wọ́n ṣe kò dáa. Àwọn míì sì máa ń gbà pé àwon ò lè ṣàṣeyọrí. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí wọ́n máa rántí àwọn kókó pàtàkì yìí:

  • Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èèyàn máa ń ṣàṣeyọrí láyé yìí.​—Jémíìsì 3:2.

  • Ìṣòro lè dé bá ẹnikẹ́ni nígbàkigbà. ​—Oníwàásù 9:11.

  • Tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, ó yẹ ká gba ìtọ́sọ́nà àwọn míì.​—Òwe 9:9.

Tí ọmọ rẹ bá ní ìforítì, ó máa jẹ́ kó lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé pẹ̀lú ìgboyà.

BÓ O ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ RẸ NÍ ÌFORÍTÌ

Tí ọmọ rẹ bá ní ìjákulẹ̀.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde, àmọ́ àjálù yóò mú kí ẹni burúkú ṣubú pátápátá.”​—Òwe 24:16.

Fi ọmọ rẹ lọ́kàn balẹ̀ kó lè mọ̀ pé àwọn ìṣòro kan ò le tó bó ṣe rò. Bí àpẹẹrẹ, kí ni ọmọ rẹ máa ṣe tó bá fìdí rẹmi nínú ìdánwò tí wọ́n ṣe nílé ìwé? Ó lè sọ pé: “Ó ti sú mi jàre!”

O ní láti kọ́ ọ ní ohun tó lè ṣe táá fi sunwọ̀n sí i nígbà míì, ìyẹn á jẹ́ kó lè ní ìforítì. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òun náà á mọ béèyàn ṣe ń kojú ìṣòro dípò táá fi jẹ́ kí ìṣòro bo òun mọ́lẹ̀.

Àmọ́, má ṣe máa bá ọmọ rẹ yanjú ìṣòro rẹ̀ nígbà gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́ ọ bó ṣe lè yanjú ìṣòro náà fúnra rẹ̀. O lè bi í pé, “Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ lóye iṣẹ́ tí wọ́n ń kọ́ ẹ nílé ìwé?”

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.”​—Jémíìsì 4:14.

Kò sí ohun tó dájú láyé yìí. Olówó òní lè di aláìní bó dọ̀la, ẹni tí ara ẹ̀ le lónìí lè dùbúlẹ̀ àìsàn lọ́la. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun, nítorí ìgbà àti èèṣì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”​—Oníwàásù 9:11.

Torí pé òbí tó mọyì ọmọ ni ẹ́, ó dájú pé wàá ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ ewu. Àmọ́ ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni òbí lè dáàbò bo ọmọ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí.

Lóòótọ́, torí pé ọmọ rẹ ṣì kéré, kò tíì lè ní àwọn ìṣòro bíi àìníṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀. Síbẹ̀, o lè ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè jẹ́ kó mọ ohun tó lè ṣe tí àárín òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan bá dà rú tàbí tí ẹnì kan bá kú nínú ìdílé. *

Tí wọ́n bá ní kí ọmọ rẹ ṣiṣẹ́ lórí ohun kan.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Fetí sí ìmọ̀ràn . . . kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.”​—Òwe 19:20.

Tí ẹnì kan bá ní kí ọmọ rẹ ṣiṣẹ́ lórí ohun kan, kì í ṣe pé ẹni yẹn ń ṣàríwísí ọmọ rẹ, àmọ́ ńṣe ló fẹ́ rà án ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ṣàtúnṣe lórí ohun náà.

Tó o bá ń kọ́ ọmọ rẹ láti máa gba ìmọ̀ràn, ó máa ṣe ẹ̀yin méjèèjì láǹfààní. Bàbá kan tó ń jẹ́ John sọ pé: “Tí ọmọ ò bá ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, kò ní gbọ́n. Ṣe ni á máa ti orí ìṣòro kan bọ́ sí òmíì, àwọn òbí náà kò sì ní sinmi bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti bá a yanjú ìṣòro náà. Èyí lè mú kí ayé sú ọmọ náà àti òbí rẹ̀.”

Báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti mọyì èrò àwọn míì tí wọ́n bá ní kó ṣiṣẹ́ lórí ohun kan? Tó bá jẹ́ pé ilé ìwé tàbí ibò míì ni wọ́n ti fún un ní ìmọ̀ràn, má sọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ìmọ̀ràn náà kò tọ́ sí ọmọ rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè béèrè lọ́wọ́ ọmọ rẹ pé:

  • “Kí lo rò pé ó fà á tí wọ́n fi fún ẹ ní ìmọ̀ràn yẹn?”

  • “Báwo lo ṣe lè sunwọ̀n sí i?”

  • “Kí lo máa ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀?”

Rántí pé tí ọmọ rẹ bá ń gba ìmọ̀ràn, ó máa ṣàǹfààní fún un ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

^ ìpínrọ̀ 21 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà,” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2008.