Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 1 2023 | Àwọn Èèyàn Ti Ba Ayé Yìí Jẹ́ Gan-An!—Ṣé Ọ̀nà Àbáyọ Wà?

Kò dìgbà téèyàn bá ka tìfuntẹ̀dọ̀ ìwé kó tó mọ̀ pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àlà. Bí àpẹẹrẹ, kò fi bẹ́ẹ̀ sí omi tó ṣeé mu mọ́, àwọn èèyàn ti ba omi òkun jẹ́, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gé gbogbo igi tán nígbó, afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú pàápàá ti bà jẹ́. Ṣé àwọn èèyàn ò ní ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe báyìí? Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá ọ̀nà àbáyọ wà.

 

Omi Tó Mọ́

Ètò wo ni Ọlọ́run ti ṣe tí kò ní jẹ́ kí omi tán nínú ayé láéláé?

Òkun

Ṣé àwọn èèyàn ti ba omi òkun jẹ́ kọjá àtúnṣe?

Igbó Kìjikìji

Kí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kíyè sí lẹ́nu àìpẹ́ yìí lẹ́yìn tí wọ́n sàyẹ̀wò àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti gé igi kúrò?

Afẹ́fẹ́

Àkóbá kékeré kọ́ ni afẹ́fẹ́ olóró ń ṣe fáwọn ohun alààyè. Ètò wo ni Ọlọ́run ti ṣe kí afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú lè tura, kó má sì pa wá lára?

Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé

Kí ló mú kó dá wa lójú pé ayé yìí máa wà títí láé á sì dùn-ún gbé?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ oríṣiríṣi ohun táwọn èèyàn ti ṣe láti bá ayé yìí jẹ́, kó o sì rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ọ̀nà àbáyọ wà.