Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inú Ọlọ́run tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” máa ń dùn láti gbọ́ wa.​—SÁÀMÙ 65:2

Máa Gbàdúrà Kó O Lè Rí Ojú Rere Ọlọ́run

Máa Gbàdúrà Kó O Lè Rí Ojú Rere Ọlọ́run

Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹ̀bùn náà ni pé a lè bá a sọ̀rọ̀, a sì lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún un. Wòlíì Dáfídì gbàdúrà pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn yóò wá.” (Sáàmù 65:2) Àmọ́ báwo la ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà wa, tí á sì bù kún wa?

FI ÌRẸ̀LẸ̀ GBÀDÚRÀ LÁTỌKÀN WÁ

Tó o bá ń dá gbàdúrà, wàá láǹfààní láti tú ọkàn rẹ jáde níwájú Ọlọ́run, wàá sì sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ fún un. (Sáàmù 62:8) Ohun tí Olódùmarè fẹ́ ni pé ká máa fi òótọ́ inú gbàdúrà látọkàn wá.

MÁA LO ORÚKỌ ỌLỌ́RUN NÍNÚ ÀDÚRÀ RẸ

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, orúkọ kan ṣoṣo ló ní. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn.” (Àìsáyà 42:8) Orúkọ náà Jèhófà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà. Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì lo orúkọ Ọlọ́run. Ábúráhámù sọ pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, . . . jẹ́ kí n máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ [pẹ̀lú rẹ].” (Jẹ́nẹ́sísì 18:30) Ó yẹ káwa náà máa lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, nínú àdúrà wa.

O LÈ GBÀDÚRÀ NÍ ÈDÈ ÀBÍNIBÍ RẸ

Èdè yòówù ká fi gbàdúrà, Ọlọ́run mọ èrò ọkàn wa àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Ìṣe 10:​34, 35.

Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún wa, àdúrà nìkan kò tó. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa mọ ohun tó yẹ ká ṣe.