Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2024 | Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa

Báwo lo ṣe lè mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ohun tọ́kàn wọn bá ṣáà ti ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n máa ń ṣe, àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé ohun tójú wọn ti rí ló máa ń mú kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Ní ti àwọn kan, ohun táwọn èèyàn bá sọ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Ìwọ ńkọ́? Kí ló máa ń jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ohun tó o fẹ́ ṣe dáa àbí kò dáa? Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn ìpinnu táá ṣe ìwọ àti ìdílé ẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú?

 

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ọ̀rọ̀ Tó Kan Gbogbo Èèyàn

Kí ló máa jẹ́ kó o mọ ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa?

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Ṣe

Ó lè jẹ́ pé ohun tó wù wá tàbí ohun táwọn èèyàn rò la fi ń pinnu bóyá ohun kan dáa àbí kò dáa. Àmọ́, ṣe amọ̀nà mí ì tún wà tá a lè gbára lé?

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú

Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣeé gbára lé?

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ìmọ̀ràn Tó Wúlò

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí mẹ́rin lára àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́, tó sì jẹ́ kí wọ́n gbà pé Bíbélì ṣeé fọkàn tán.

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tó dáa, tó ò sì ní kábàámọ̀ tó bá yá.