Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jésù fi dẹ́bi fún àwọn tó ń búra?

NÍBÀÁMU pẹ̀lú Òfin Mósè, àwọn ìgbà kan wà táwọn Júù lè búra. Àmọ́ nígbà ayé Jésù, wọ́n ti ṣi àǹfààní náà lò débi pé kò sóhun tí wọ́n sọ tí wọn kì í búra sí. Ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́. Àmọ́, ẹ̀ẹ̀mejì ni Jésù dẹ́bi fún àṣà yìí. Ó sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.”​—Mát. 5:​33-37; 23:​16-22.

Ìwé kan tó ń jẹ́ Theological Dictionary of the New Testament, tọ́ka sí ìwé Talmud tó jẹ́ ìwé ìsìn àwọn Júù. Ìwé Talmud yìí jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ohun táwọn Júù kì í búra sí. Ìwé náà tún ṣàlàyé irú àwọn ìbúra tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ àtàwọn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀.

Kì í ṣe Jésù nìkan ló dẹ́bi fún àṣà yìí. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Flavius Josephus náà sọ nípa àwọn ẹ̀yà Júù kan tó kórìíra kéèyàn máa búra. Àwọn ẹ̀yà yẹn gbà pé kéèyàn búra burú ju kéèyàn parọ́ lọ. Wọ́n gbà pé tó bá ti di pé kéèyàn búra kí wọ́n tó lè gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, a jẹ́ pé onírọ́ ni onítọ̀hún. Ìwé àpókírífà àwọn Júù kan tí wọ́n ń pè ní Wisdom of Sirach tàbí Ecclesiasticus, (23:11) náà sọ pé: “Aláìdáa èèyàn lẹni tó bá ń búra nígbà gbogbo.” Torí náà, Jésù dẹ́bi fún àwọn tó ń búra lórí ohun tí kò ní láárí. Tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà la máa ń sòótọ́, kò dìgbà tá a bá búra káwọn èèyàn tó gbà pé òótọ́ la sọ.