Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orúkọ Bíbélì Kan Tó Wà Lára Ìkòkò

Orúkọ Bíbélì Kan Tó Wà Lára Ìkòkò

Lọ́dún 2012, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn àfọ́kù ìkòkò amọ̀ kan tọ́jọ́ ẹ̀ ti pẹ́ gan-an, kódà ó ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún. Àfọ́kù ìkòkò yìí ti wá di ìran àpẹ́wò fáwọn olùṣèwádìí. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára àfọ́kù ìkòkò náà ló mú káwọn èèyàn máa kọ hàà.

Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn jàjà rí àfọ́kù náà tò jọ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ó wá ṣeé ṣe fún wọn láti ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi èdè àwọn ará Kénáánì ìgbàanì kọ sára ìkòkò náà. Ohun tó wà lára ìkòkò náà ni: “Eṣibáálì ọmọ Beda.” Ìgbà àkọ́kọ́ rèé táwọn awalẹ̀pìtàn máa rí i pé wọ́n kọ orúkọ yìí sára ohun ìsẹ̀ǹbáyé kan.

Ẹlòmíì náà wà nínú Bíbélì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eṣibáálì, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọba Sọ́ọ̀lù. (1 Kíró. 8:33; 9:39) Ọ̀jọ̀gbọ́n Yosef Garfinkel, tó wà lára àwọn tó ṣàwárí ìkòkò náà sọ pé: “Ó wúni lórí gan-an pé orúkọ náà Eṣibáálì tá a rí lára ìkòkò tá a wú jáde yìí wà nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ lásìkò tí Ọba Dáfídì ṣàkóso nìkan lorúkọ náà fara hàn.” Kódà, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé àsìkò yẹn làwọn èèyan máa ń jẹ́ orúkọ náà. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ẹ wo bí ohun tí wọ́n ṣàwárí yìí ṣe tún jẹ́rìí sí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì!

Ibòmíì tún wà nínú Bíbélì tí orúkọ náà Eṣíbáálì ti fara hàn, àmọ́ Iṣi-bóṣẹ́tì ni wọ́n pè é. (2 Sám. 2:10) Kí nìdí tí wọ́n fi “bóṣẹ́tì” rọ́pọ̀ “báálì” tó wà nínú orúkọ náà? Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé: “Ó jọ pé ẹni tó kọ ìwé Sámúẹ́lì kejì kò fẹ́ lo Eṣíbáálì torí pé ìyẹn máa mú káwọn èèyàn Ọlọ́run rántí òrìṣà Báálì, táwọn ará Kénáánì gbà pé òun ló máa ń rọ̀jò. Àmọ́ orúkọ yẹn gangan lẹni tó kọ̀wé Kíróníkà kọ ní tiẹ̀.”