Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ẹyẹ Godwit Ṣe Ń Rìnrìn Àjò

Bí Ẹyẹ Godwit Ṣe Ń Rìnrìn Àjò

ẸYẸ godwit, èyí tí ìyẹ́ ìdí rẹ̀ máa ń ṣù pọ̀, wà lára àwọn ẹyẹ tó máa ń ṣí láti ibì kan lọ sí ibòmíì lọ́nà tó yani lẹ́nu gan-an. Ó máa ń rin ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá [11,000] kìlómítà fún ohun tó lé ní ọjọ́ mẹ́jọ gbáko.

Rò Ó Wò Ná: Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé àwọn ẹyẹ kan máa ń lo agbára òòfà ilẹ̀ ayé láti fi mọ apá ibi tí wọ́n máa forí lé nígbà tí wọ́n bá ń fò. Ìyẹn sì wá mú kó dà bíi pé wọ́n ní irinṣẹ́ tí bàlúù fi ń fò nínú ọpọlọ wọn. Ó tún ṣeé ṣe kí ẹyẹ yìí máa lo ìtànṣán oòrùn lọ́sàn-án kó sì máa lo ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ ní òru nígbà tó bá ń rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn yẹn. Ó tún ṣeé ṣe kó mọ apá ibi tí atẹ́gùn máa fẹ́ sí, kó sì jẹ́ kí atẹ́gùn máa darí òun. Síbẹ̀ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa bí àwọn ẹyẹ yìí ṣe máa ń rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn ṣì máa ń ya àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́nu. Ọ̀gbẹ́ni Bob Gill tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ohùn alààyè sọ pé: “Ó ti pé ogún [20] ọdún báyìí tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹyẹ yìí, àmọ́ síbẹ̀ àgbàyanu ló ṣì máa ń jẹ́ fún mi.”

Kí Lèrò Rẹ? Ǹjẹ́ bí ẹyẹ godwit ṣe ń rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ́nà tó yani lẹ́nu yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?