Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fídíò Tó Dá Lórí Bíbélì—Ẹ̀kọ́ Pàtàkì

Àwọn fídíò kéékèèké yìí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì látinú Bíbélì, irú bíi Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú? àti Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

Ṣé Ọlọ́run Ló Dá Àgbáálá Ayé Yìí?

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá kán wà, àmọ́ ọ̀pọ̀ ò lóye àlàyé rẹ̀, wọ́n tiẹ̀ sọ pé ìtàn àròsọ ni. Ṣé a lè gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́?

Ṣé Ọlọ́run Wà Lóòótọ́?

Wàá rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run wà.

Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?

Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, lára rẹ̀ ni Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, àti Olúwa. Fídíò yìí sọ orúkọ Ọlọ́run gangan èyí tó fara hàn ní ibi tó lé ni ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Bíbélì.

Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

Tó bá jẹ́ pé èèyàn ló kọ ọ́, ṣé a wá lè pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Èrò ta ló wà nínú Bíbélì?

Ṣe Òótọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ni Bíbélì, á jẹ́ pé kò sí ìwé míì tá a lè fi í wé.

Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?

Ayé yìí rẹwà gan-an ni. Kò sún mọ́ oòrùn jù, kò sì jìnnà sí i jù, ibi tó yẹ gẹ́lẹ́ ló rọra dagun sí, ńṣe ló sì ń yípo ní ìwọ̀n tó yẹ gẹ́lẹ́. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé lọ́nà tó dára tó bẹ́ẹ̀ tó sì tún ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi sínú rẹ̀?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa jí dìde, gẹ́gẹ́ bí Lásárù ṣe jí dìde.

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Àwọn Ẹni Burúkú Máa Joró Nínú Ọ̀run Àpáàdì?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” torí náà kò lè máa dá àwọn èèyàn lóró torí àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe kọjá.

Ṣé Jésù Kristi Ni Ọlọ́run?

Ṣé Jésù Kristi ni Ọlọ́run Olódùmarè? Àbí ó yàtọ̀ sí Ọlọ́run Olódùmarè?

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ikú Jésù ṣe pàtàkì gan-an. Ṣé àǹfààní kankan wà nínú ikú Jésù?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Nígbà tí Jésù wà láyé, ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló kọ́ àwọn èèyàn jù lọ. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé.

Ọdún 1914 Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso

Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [2,600] ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run mú kí ọba kan tó jẹ́ alágbára lá àlá kan. Àlá náà jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, ó sì ti ń ṣẹ báyìí..

Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí

Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń hùwà burúkú láti ọdún 1914 fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ń ṣẹ báyìí.

Ṣé Àmúwá Ọlọ́run Làwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Àwọn méjì tí àjálù ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá sọ ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì.

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń béèrè pé kí ló fà á tí ìkórìíra àti ìyà fi pọ̀ láyé. Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn tó sì tuni nínú.

Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà.

Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Ká Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn?

Òótọ́ ni pé a ò lè rí Ọlọ́run, àmọ́ ṣé a máa túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tá a bá ń lo ère nínú ìjọsìn?

Ṣé Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́?

Tó bá jẹ́ pé tara ẹ nìkan lò ń gbà ládùúrà ńkọ́? Tí ọkọ kan bá ń fìyà jẹ ìyàwó ẹ̀, tó sì wá ń gbàdúrà fún ìbùkún Ọlọ́run ńkọ́?

Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rí?

Ọlọ́run fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ̀ dùn bí oyin. Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ tọkọtaya lọ́wọ́.

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Jẹ́ Lójú Ọlọ́run?

Ṣé ọ̀rọ̀ náà “àwòrán ìṣekúṣe” tiẹ̀ wà nínú Bíbélì? Báwo la ṣe lè mọ bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe rí lójú Ọlọ́run?