Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìtọ́ni fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Ìtọ́ni fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

1. Àwọn ìtọ́ni tó wà nínú ìwé yìí á ran gbogbo àwọn tó níṣẹ́ ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́wọ́. Ẹ ka àwọn ìtọ́ni tó wà fún iṣẹ́ yín èyí tá a kọ sínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àti sínú ìwé yìí kẹ́ ẹ tó múra iṣẹ́ yín sílẹ̀. A gba gbogbo àwọn akéde níyànjú pé kí wọ́n se tán láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Àwọn míì tó bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé náà lè ṣiṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, tí wọ́n bá fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wọn. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ẹni tí kìí ṣe akéde tó wù láti di ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jíròrò àwọn ohun tí ẹni náà máa ṣe kó lè kúnjú ìwọ̀n láti di ọmọ ilé ẹ̀kọ́, kó sì jẹ́ kó mọ̀ tó bá kúnjú ìwọ̀n. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ẹni náà jíròrò níṣojú ẹni tó ń bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (tàbí níṣojú òbí rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni). Àwọn ohun kan náà tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi náà là ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́ pẹ̀lú.—od orí 8 ìpínrọ̀ 8.

 Ọ̀RỌ̀ ÌBẸ̀RẸ̀

2. Ìṣẹ́jú kan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn orin àti àdúrà, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sọ ohun tá a mú kí àwùjọ fojú sọ́nà láti gbádùn ìpàdé náà. Àwọn kókó tó ṣe pàtàkì tó máa ṣe ìjọ láǹfààní jù ni kí alága mẹ́nu bà.

  ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 3. Àsọyé: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Àkòrí àsọyé yìí àtàwọn kókó pàtàkì méjì sí mẹ́ta máa wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ní ọ̀sẹ̀ tá a bá bẹ̀rẹ̀ ìwé Bíbélì tuntun, a máa wo fídíò kan tó máa sọ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì náà. Olùbánisọ̀rọ̀ lè sọ bí ohun tó wà nínú fídíò náà ṣe tan mọ́ àkòrí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kó rí i pé òun bójú tó àwọn kókó tó wà nínú ìwé ìpàdé náà. Bí àkókò bá ṣe wà sí, kó fara balẹ̀ ṣàlàyé àwọn àwòrán tá a dìídì fi síbẹ̀ kí ẹ̀kọ́ náà lè túbọ̀ yéni. Ó tún lè tọ́ka sí àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde míì, tó bá ṣáà ti bá àwọn kókó tó wà nínú ìwé ìpàdé náà mu.

 4. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Apá yìí jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn tí kò ní ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ìparí. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó o. Kó bi àwùjọ láwọn ìbéèrè méjèèjì tó wà nínú ìwé ìpàdé. Bákan náà, òun ló máa pinnu bóyá a máa ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ tàbí a ò ní kà á. Kí àwọn tó máa dáhùn ní apá yìí ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀.

 5. Bíbélì Kíkà: Ìṣẹ́jú mẹ́rin. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin ni kó ṣiṣẹ́ yìí. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ka ibi tá a yàn fún un láìsí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìparí. Kí alága ìpàdé ní in lọ́kàn láti ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ láti kàwé bó ṣe yẹ, lọ́nà tó yéni yékéyéké, tó já geere àti pẹ̀lú ìtẹnumọ́ tó yẹ. Kó jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa yí ohùn pa dà bó ṣe tọ́, bí wọ́n á ṣe máa dánu dúró níbi tó yẹ, tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn. Nítorí pé àwọn ẹsẹ tá a yàn fún Bíbélì kíkà máa ń gùn jura lọ, kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ronú nípa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe mọ̀wé kà tó kó tó yan iṣẹ́ fún un.

 TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

6. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. A dìídì ṣe apá yìí kó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù, kí ọ̀nà tá a ń gbà fọ̀rọ̀ wérọ̀, wàásù, àti bá a ṣe ń kọ́ni lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Bó ba yẹ bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà lè ṣiṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ṣiṣẹ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ tá a mú látinú ìwé Kíkọ́ni tàbí nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, eyí tá a kọ́ sínú àkámọ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ tá a yàn fún un nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Nígbà míì, apá tó jẹ́ ìjíròrò lè wà nínú ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó iṣẹ́ yẹn.—Wo  ìpínrọ̀ 15 nípa bá a ṣe máa bójú tó apá tó bá jẹ́ ìjíròrò.

 7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin, tàbí ara ìdílé ẹni náà. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró.—Fún ìsọfúnni síwájú síi nípa ohun tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa sọ àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, wo  ìpínrọ̀ 12 àti  13.

 8. Pa Dà Lọ: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. (km 5/97 ojú ìwé 2) Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàfihàn ohun tá a lè sọ láti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìjíròrò wa.—Fún ìsọfúnni síwájú síi nípa ohun tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa sọ àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, wo  ìpínrọ̀ 12 àti  13.

 9. Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. (km 5/97 ojú ìwé 2) Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró. Apá yìí jẹ́ àṣefihàn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ lọ́wọ́. Kò ní sí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìparí àyàfi tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ń ṣisẹ́ lórí ọ̀kan nínú àwọn kókó ẹ̀kọ́ yẹn. Kò pọn dandan kí á ka gbogbo ìpínrọ̀ náà jáde nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò burú láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 10. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́:Tí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ àsọyé, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin ni kó ṣe é. Tó bá jẹ́ àṣefihàn, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin lè ṣe é. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin, tàbí ara ìdílé ẹni náà. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ fọgbọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà fún àpá yìí lọ́nà tó ṣe kedere, kó sì lo àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a tọ́ka sí. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ló ma pinnu bóyá òun máa mẹ́nu ba ìtẹ̀jáde tá a ti mú àwọn ìsọfúnni tá a tọ́ka sí nígbà tó bá ń ṣe iṣẹ́ yìí.

 11. Àsọyé: Àsọyé fún ìjọ ni kí apá yìí jẹ́, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin sì ni kó ṣe é. Tá a bá gbé àsọyé náà ka kókó kan nínú àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sọ bí a ṣe lè lo àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣàlàyé ìgbà tá a lè lo ẹsẹ Bíbélì kan, ìtumọ̀ ẹ, àti bá a ṣe lè mú kí ẹnì kan ronú lórí ẹ̀. Tá a bá gbé àsọyé náà ka orí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sọ bá a ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ náà nígbà tá a bá ń wàásù. Ó lè lo àpẹẹrẹ tó wà ní kókó kínní ẹ̀kọ́ náà tàbí ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà.

   12. Ohun Tí Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Sọ: Ìsọfúnni tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e wà fún iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tá a pè ní “Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa” àti “Pa Dà Lọ”. Àfojúsùn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ni láti ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì kan tó wúlò, tó sì rọrùn lóye pẹ̀lu ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀, kó sì sọ ohun tá á bá ẹni náà jíròrò nígbà tó bá pa dà lọ, àyàfi tí ìtọ́ni tó wà fún ìpàdé bá ní kó ṣe nǹkan míì. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mú kókó tó bágbàmu, tó sì máa wúlò ní àdúgbò yín. Ó lè pinnu bóyá kóun lo ìtẹ̀jáde tàbí fídíò èyíkéyìí tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Dípò kí wọ́n há iṣẹ́ wọn sórí, ṣe ni kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gbé ọ̀nà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ jáde, bíi jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wọ́n lógún àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn.

   13. Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀: Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n yàn fún un bá ti àdúgbò yín mu. Bí àpẹẹrẹ:

  1. (1) Ilé dé Ilé: Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí ní wíwàásù láti ilé dé ilé—yálà lójúkojú, lórí fóónù, tàbí lẹ́tà kíkọ —àti pípadà lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé nínú.

  2. (2) Ìwàásù Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà: Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí dá lórí bá a ṣe lè lo àǹfààní ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ láti jẹ́rìí fún àwọn tá à ń bá pàdé. Ẹ lè jíròrò kókó kan látinú Bíbélì pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ pàdé lẹ́nu iṣẹ́, ní ilé ìwé, ládùúgbò, nínú ọkọ̀ èrò, àti níbò míì bẹ́ ẹ ṣe ń bá ìgbòkègbodò yín ojoojúmọ́ lọ.

  3. (3) Wíwàásù Níbi Térò Pọ̀ Sí: Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí lè ní wíwàásù pẹ̀lú àtẹ ìwé, wíwàásù níbi táwọn èèyàn tí ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, ìjẹ́rìí òpópónà, tàbí wíwàásù láwọn ibi ìgbafẹ́, ibi ìgbọ́kọ̀sí àti láwọn ibòmíì táwọn èèyàn máa ń wà nínú.

 14. Bá A Ṣe Máa Lo Àwọn Fídíò àti Ìtẹ̀jáde: Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lè pinnu bóyá kóun lo fídíò tàbí ìtẹ̀jáde kan, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Tí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ní fídíò tàbi tó pinnu láti lò ó, kó nasẹ̀ fídíò náà, kó sì ṣàlàyé ẹ̀, sùgbón kí wọ́n má ṣe wò ó.

  MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

15. A máa fi orin bẹ̀rẹ̀ apá yìí. Lẹ́yìn náà, a máa ṣe iṣẹ́ kan tàbí méjì, ó sì máa gba ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15]. Apá yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí àyàfi tó bá jẹ́ ohun tó ń fẹ́ àbójútó lẹ fẹ́ jíròrò. Alàgbà ni kó bójú tó o. Tí apá yìí bá ní iṣẹ́ tó jẹ́ ìjíròrò nínú, olùbánisọ̀rọ̀ lè béèrè àwọn ìbéèrè míì láfikún sí àwọn ìbéèrè tó wà fún iṣẹ́ náà. Kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ má gùn, kí àkókò lè tó láti mú kókó ọ̀rọ̀ jáde, kí àwùjọ sì lóhùn sí i. Tí iṣẹ́ náà bá ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, á dáa kí ẹni tí wọ́n ń fọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò sọ̀rọ̀ látorí pèpéle, tó bá ṣeé ṣe.

  16. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Alàgbà tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó apá yìí. (Tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó nínú ìjọ yín, ẹ lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.) Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan àwọn tó tóótun láti darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Àwọn tá a bá yàn gbọ́dọ̀ lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́nà tó nítumọ̀; kí wọ́n má bàa kọjá àkókò, kí wọ́n sì lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ á fi ṣe kedere. Kí olùdarí ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe fi àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì náà sílò. Àwọn tá a bá yàn láti darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ á rí àwọn ìlànà tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó dára láti gbà darí apá tó ní ìbéèrè àti ìdáhùn.( w23.04 ojú ìwé 24, àpótí) Kò pọn dandan kẹ́ ẹ fa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá tí jíròrò gbogbo kókó tó wà ní apá tá a yàn fún ọ̀sẹ̀ náà. Tó bá ṣeé ṣe, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà sì ni kó máa kàwé. Tí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ní kí ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ dín àkókò tó yẹ kó fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀ kù, ọwọ́ ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ló kù sí láti mọ bó ṣe máa dín àkókò náà kù. Ó lè pinnu pé a ò ní ka àwọn ìpínrọ̀ kan.

  Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ

17. Ìṣẹ́jú mẹ́ta. Alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì táá ran ìjọ lọ́wọ́, á sì tún sọ ohun tá a máa kọ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Tí àkókò bá sì wà, ó lè ka orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó máa níṣẹ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Àárín ìṣẹ́jú mẹ́ta yìí náà ni alága ìpàdé máa ṣe ìfilọ̀ tàbí ka lẹ́tà tó pọn dandan, àyàfi tẹ́ ẹ bá gba ìtọ́ni míì. Ẹ má ṣèfilọ̀ àwọn ohun tá a máa ń ṣe látìgbàdégbà bíi ètò fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba lórí pèpéle, pátákó ìsọfúnni ni kẹ́ ẹ lẹ̀ wọ́n mọ́. Tí ìṣẹ́jú mẹ́ta tí alága fi máa sọ ọ̀rọ̀ ìparí yìí kó bá ní tó láti ṣe ìfilọ̀ tàbí ka lẹ́tà, kí alága sọ fún àwọn arákùnrin tó níṣẹ́ ní apá Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni pé kí wọ́n dín àkókò tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ wọn kù. (Wo  ìpinrọ̀ 16 àti  19.) Kẹ́ ẹ fi orin àti àdúrà parí ìpàdé náà.

  ÌṢÍRÍ ÀTI ÌMỌ̀RÀN

18. Lẹ́yìn tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan bá ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ tán, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lo ìṣẹ́jú kan péré láti gbóríyìn fún ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà, kó sì fún un nímọ̀ràn tó dá lórí kókó ẹ̀kọ́ tí a yàn fún un láti ṣiṣẹ́ lé lórí. Nígbà tí alága bá ń pe ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kàn láti wá ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò ní sọ kókó ẹ̀kọ́ tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà bá ti parí iṣẹ́ rẹ̀, tí alága sì ti gbóríyìn fún un, ó lè sọ kókó ẹ̀kọ́ tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣiṣẹ́ lé lórí. Kó sọ ìdí tó fi sọ pé ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe dáadáa lórí kókó yẹn tàbí kó sọ ìdí tó fi yẹ kó fún kókó náà láfiyèsí sí i àti bó ṣe lè ṣe é. Kí alága ìpàdé ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Alága ìpàdé tún lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó míì nínú àṣefihàn náà tó mọ̀ pé á ṣe ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà tàbí àwùjọ láǹfààní. Nígbà míì, ó lè pọn dandan pé kí alága tún bá ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tàbí lásìkò míì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí alága lo ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, ìwé Kíkọ́ni tàbí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti jẹ́ kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà mọ bó ṣe lè sunwọ̀n sí i lórí kókó ẹ̀kọ́ tí wọ́n yàn fún un tàbí láwọn apá ibò míì.—Wo àlàyé tó wà ní  ìpínrọ̀ 19,  24, àti  25 fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ojúṣe alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti ti olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn.

     ÀKÓKÒ

19. Ẹ má ṣe kọjá àkókò tá a yàn fún apá kọ̀ọ̀kan, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ náà má ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa sọ àkókò tí a yan fún apá kọ̀ọ̀kan, tó o bá ti parí gbogbo kókó tó o fẹ́ jíròrò kí àkókò ẹ tó pé, kò pọn dandan kó o fa iṣẹ́ ẹ gùn kó o lè lo gbogbo àkókò ẹ tán. Tí apá èyíkéyìí nínú ìpàdé náà bá kọjá àkókò tá a yán fún un, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn fún ẹni tó ṣiṣẹ́ náà ní ìmọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. (Wo  ìpínrọ̀ 24 àti  25.) Kí ìpàdé náà, látì ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, títí kan orin àti àdúrà, má ṣe kọjá wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta (45).

 ÌBẸ̀WÒ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

20. Nígbà tẹ́ ẹ bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ni kẹ́ ẹ tẹ̀ lé. Ẹ fí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn ọlọ́gbọ̀n [30] ìṣẹ́jú tí alábòójútó àyíká máa sọ rọ́pò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ ní apá Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni. Kẹ́ ẹ tó gbọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn, alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ṣe àtúnyẹ̀wò ìpàdé ọjọ́ yẹn, á sì fojú àwùjọ sọ́nà fún ohun tẹ́ ẹ máa gbádùn lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, á ṣe àwọn ìfilọ̀ tó bá pọn dandan, á sì ka àwọn lẹ́tà tó bá yẹ́. Lẹ́yìn náà, á pe alábòójútó àyíká sórí pèpéle. Tí alábòójútó àyíká bá ti parí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, òun ló máa yan orin tẹ́ ẹ máa fi parí ìpàdé. Tó bá fẹ́, ó lè ní kí arákùnrin míì wá gbàdúrà ìparí. Kò ní sí kíláàsì kejì ní ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Àwùjọ tó bá ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí èdè tí ìjọ yín fi ń ṣe ìpàdé lè ṣe ìpàdé tiwọn lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò yín. Àmọ́, kí àwùjọ náà dara pọ̀ mọ́ yín kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn alábòójútó àyíká.

 Ọ̀SẸ̀ ÀPÉJỌ ÀYÍKÁ TÀBÍ TI AGBÈGBÈ

21. Ẹ ò ní ṣe ìpàdé ìjọ ní ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àyíká tàbí ti àgbègbè. Ẹ rán àwọn ará ìjọ létí pé kí wọ́n jíròrò àwọn apá ìpàdé ọ̀sẹ̀ yẹn bí ìdílé tàbí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

 Ọ̀SẸ̀ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI

22. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí àárín ọ̀sẹ̀, kò ní sí Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lọ́sẹ̀ yẹn.

 ALÁBÒÓJÚTÓ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́

23. Ìgbìmọ̀ alàgbà ló máa yan alàgbà kan tó máa jẹ́ alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ojúṣe rẹ̀ ni láti rí i pé ìpàdé yìí lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó sì rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú ìwé yìí. Òun àti olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ní láti máa forí korí látìgbàdégbà. Alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa yan gbogbo iṣẹ́ tó wà ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ fún oṣù méjì tó wà nínú ìwé ìpàdé ní gbàrà tí Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ti dé. Òun ló máa yan àwọn iṣẹ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, ẹni tó máa jẹ́ alága ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ lára àwọn tí ìgbìmọ̀ alàgbà fọwọ́ sí, ó sì tún máa yan iṣẹ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́. (Wo  ìpínrọ̀ 3-16 àti  24.) Tó bá ń pín iṣẹ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, kó gbé ọjọ́ orí, ìrírí àti bí wọ́n ṣe ní òmìnira ọ̀rọ̀ sí lórí àkòrí tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ lé yẹ̀ wò, kó tó yan iṣẹ́ fún wọn. Kó ṣe bẹ́ẹ̀ náà tó bá ń pín àwọn iṣẹ́ yòókù. Ó yẹ kí àwọn tó máa níṣẹ́ nípàdé ti mọ̀ pé àwọn níṣẹ́ ó kéré tán ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ wọn. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lo Ìwé Iṣẹ́ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni (S-89) láti fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ níṣẹ́. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ípàdé àárín ọ̀sẹ̀ wà lójú pátákó ìsọfúnni. Ìgbìmọ̀ alàgbà lè yan alàgbà míì tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti máa ràn án lọ́wọ́. Àmọ́ o, àlàgbà nìkan ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó máa yan àwọn iṣẹ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́.

    ALÁGA ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́

24. Alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lá máa ṣe alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó nínú ìjọ yín, ẹ lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.) Kó múra ọ̀rọ̀ táá fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àtèyí táá fi parí rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, òun ló máa pe àwọn tí iṣẹ́ kàn láti ṣe iṣẹ́ wọn. Òun náà lè ṣe àwọn iṣẹ́ kan lọ́sẹ̀ tó ṣe alága tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó, pàápàá àwọn apá tó bá jẹ́ pé fídíò nìkan la fẹ́ wò, tí kò sì ní ìjíròrò. Kí ọ̀rọ̀ tó máa sọ lẹ́yìn tí ẹnì kan bá parí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe ṣókí. Ìgbìmọ̀ alàgbà ló máa yan àwọn alàgbà tó tóótun láti máa ṣe alága ìpàdé. Látìgbàdégbà làwọn alàgbà tá a yàn yìí á máa ṣe alága ìpàdé Ìgbésí Ayé. Ìjọ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, àmọ́ tó bá gbà bẹ́ ẹ̀, alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lè ṣe alága ìpàdé ju àwọn alàgbà míì tí wọ́n ti yàn lọ. Tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá gbà pé alàgbà kan mọ̀ọ̀yàn kọ́ débi táá fi máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, á jẹ́ pé alàgbà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alága ìpàdé náà. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi sọ́kàn pé alàgbà tó máa ṣe alága ìpàdé ní láti mọ bí a ṣe ń fìfẹ́ gbóríyìn fún àwọn tó ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àti fífìfẹ́ gbà wọ́n nímọ̀ràn nípa ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ojúṣe rẹ̀ ni láti rí i pé ìpàdé parí lásìkò. (Wo  ìpínrọ̀ 17 àti  19.) Bí alága bá fẹ́, tí àyè rẹ̀ sì wà, ẹ lè ṣètò makirofóònù kan tó dá dúró sí apá kan pèpéle, látibẹ̀ á máa pé àwọn tó níṣẹ́, tí àwọn yẹn á sì ti wà nibi tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ tá a ṣètò fún wọn. Tí alága ìpàdé bá fẹ́, ó lè jókòó sídìí tábìlì kan lórí pèpéle nígbà Bíbélì kíkà àti ní apá Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù. Ìyẹn ò ní jẹ́ ká fàkókò ṣòfò.

   OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN

25. Ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fi alàgbà tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa ṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Ojúṣe rẹ̀ ni láti máa fún àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí nímọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Èyí kan apá tí wọ́n bá bójú tó nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àsọyé fún gbogbo ènìyàn, dídarí tàbí kíkàwé nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. (Wo  ìpínrọ̀ 19.) Bí àwọn alàgbà tí wọ́n lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá bá pọ̀ ní ìjọ yín, ẹ lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó bá kúnjú ìwọ̀n lọ́dọọdún láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà táwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ṣiṣẹ́ ni olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn máa fún wọn nímọ̀ràn.

 KÍLÁÀSÌ KEJÌ

26. Bí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu bóyá kẹ́ ẹ ní kíláàsì kejì. Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan ẹni tó tóótun fún kíláàsì kejì yìí; ó máa dáa kó jẹ́ alàgbà. Àmọ́ níbò míì, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun lè ṣe iṣẹ́ náà. Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan ẹni táá máa bójú tó iṣẹ́ yìí, kí wọ́n sì pinnu bóyá ẹni kan lá máa ṣe é tàbí ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lá máa ṣe é. Àlàyé tá a ṣe ní  ìpínrọ̀ 18 ni kí ẹni náà tẹ̀ lé, Tẹ́ ẹ bá ní kíláàsì kejì, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti parí apá tá a pè ní Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì ní abala Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ni káwọn tó máa ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kọjá sí ibi tí wọ́n á ti ṣe é. Kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ pa dà lẹ́yìn iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó gbẹ̀yìn.

 ÀWỌN FÍDÍÒ

27. A ti ṣètò àwọn fídíò kan tí àá máa lò nínú ìpàdé yìí. Ẹ máa rí àwọn fídíò náà lórí JW Library®, ẹ lè fi oríṣiríṣi ẹ̀rọ wo àwọn fídíò náà.

© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

S-38-YR 11/23